Eji Gboro

From Wikipedia

Eji Gboro

For the complete work, see OKAN-O-JOKAN AROFO at www.researchinyoruba.com

ÈJÌ GBÒRÒ

Mo ti rìn

Mo rìn jìnà réré

Mo délèe Kùsà

Mo dé Kútíwenji

Mo délè Àgàn-ìn 5

Mo dé ti Sàró

Mo gba Dàhòmì bò

Mo wojà wò

N tóó bomi jótí

N ò sì gbàgbé láti belè wò 10

Torí se lewúré ń bele wò

Kó tóó jókòó

Esinsin-ìn bá olóde rìn

Kò sùn lébi

Mo topa odò tí kò kún 15

Mo pàdé Olúweri

Olúweri wáá pè mí kàsá

Ó ní n jé mo se àkíyèsí

Pé èjì gbòrò lOlórun ń dáhun gbogbo

Èmi náà wáá ronú jinlè 20

Mo lóòótó mà ni

Méjì mejì lohun gbogbo ń rìn

Torí tesè, tapá titan

Tojú timú, tinú tèyìn

Tibi tire, tèdò tìfun 25

Tako tabo, tàgbà tèwe

Oko aya, ègbón àbúrò

Baba omo, òré òtá

Mo wò títí

Mo lanu, n ò lè pa á dé 30

Mo ló o kú ogbón Olúweri

Mo lópò nnkan ló wà

Tí n ò lè dárúko

Tó jé pé tá a bá dárúko òkan

Èkejì á so sí wa lókàn 35

Mo ní káábíyèsí

Obaà mi Èdùmàrè

Oba asohun bó ti tó.