Iku Olowu

From Wikipedia

Iku Olowu Iku Olowu

Contents

[edit] ÌRAN KÌN-ÍN-NÍ

(NÍ ÌDÍ MÒGÚN NÍ ÌLÚ ÒGÙDÙ)

(Iná tàn, a sì ri Òrìsà Mògún. Wón ti té gbogbo ohun  èlò ìbo sí ìdi 

òrìsà náà. A bèrè sí níí gbó orin àwon olùsìn Mògún láti èyin ìtàgé)

Orin: Mògún o sé o, onílé orókè, a dúpé dúpé. A kò jé fògèdè móyán e, a kò jé fisu lásán bo é mó. Bá wa gbékú lo, kó o gbárùn lo. Mògún onírè, baba, ìwo la ó máa sìn o. (Igbà tí won yóò fi ko orin dé ibí yìí, àwon olùsin Mògún ti ń yo sí orí ìtàgé. Síbè, won kò dákè orin àti ijó)

Orin: Ajá ńlá lo ń wá, a ó wá a, a ó fi sàwárí. Lákolábo, ajá ńlá, lo ń fé tá a ó fi sètùtù o, ètùtù owó, a ó se ètùtù omo.Wá, wá, wá, Mògún o, wá bá wa sàseyorí. Lónílé lálejò, ká má se kábàmò, gbopé wa. Ìwo la ó máa sìn o.(Ó joún pé Mògún ti se àwon ènìyàn wònyí lóore gidi ni. Bí wón se ń to ni wón ń fò bí olè tí ó gbé òké ìyere tí ó se bí owó ni. Ó se sá, Olùbo dé, ó sì dá won ní ménu).

Olùbo: Ó tó (gbogbo won dáké).A dúpé lówó Mògún pé a se odún yìí, á ó sé èèmíìn. Àbí, bá a bá se ní lóore opé káà á dá bí? Wón ní eni tí a se lóore tí kò dúpé, bí a se elèyún-ùn níkà ni kò léèwò. Sé òhun náà ni Yorúba rò pò tó fi so pé ènìyàn yin-ni-yin-ni, kéni sèmíìn.

Àwon Olùsìn: Opé náà la wá fi fún Mògún lónìí.

Olùbo: Èmi á dúpé tèmi, èmi á dúpé tèmi, tá a bá seni lóore, opé là á dá o (ìlú so)

Àwon Olùsìn: Èmi á dúpé tèmi

Olùbo: Tá a bá seni lóore, opé là á dá o

Àwon Olùsìn: Èmi á dúpé tèmi

Olùbo: Ò tó. (Àwon olùsin dáké) Òrò mì ò ní í pò lójó òní, àròyé mí dòla, ojó ire, tórí opé ni mo wá fi ojó òní dá bí mo se só. Àdúà ni mo wá fojó òní gbà. Se ni a kúkú n kobè sílè, Mògún ló meni tí yóò jesu. A ti je todún tó kojá, a dúpé, a tópé dá. A kì í da fíríì ká má wàkè, méjèèjì la ti se lódún èsí, kò se wá níhun páà, a fopé fún Mògún. Àmó, báwo lodún tuntun yìí yóò se rí? N náà la wá bèèrè. Bí ìségun yóò tile wà, kì í se láti owó idà fúnra rè bí kò se láti owó eni tó mú un dání. Àwa sì nidà, Mògún ni jagunjagun tó mú wa dání, àbí béè kó?

Àwon Olùsìn: Béè ni

Olùbo: Gégé bí ìse wa, kí á tó bèrè ìbo òní, Mògún náà la ó bi léèrè bí nnkan yóò se rí.

Àwon Olùsìn: Béè ni, o wíire

Olùbo: (Ó kojá sí ìdi Mògún pèlú obì ajóòópá lówó) N gbó Mògún, àwon àgbà ló ní ikun níi fagbárí selé, kèlèbè níí fònà òfun sòòdè, tòjòtèèrùn, imú ajá kì í gbe, tòjòtèèrùn. Njé tá a bá jí wolé ajé, tá a pajé, sé kájé gbó? Mo ní sé tá a bá se kùtù wolé ayò, omo onílé oyin, tá a á pè é, sé kó gbà? (Ó da obì owó rè, obì fore, ó fi ariwo bonu) Mògún yè.

Àwon Olùsìn: Yèèè.

Olùbo: Mògún yèèèè.

Àwon Olùsìn: Yèèèè (Okùnrin kan yo sí orí ìtàgé. Ó wo aso Òyìnbó ó sì dàpò mó àwon ènìyàn, sùgbón wón ti rí i. Kíá, ìlú ti so, orin ti bèrè, ó joun pé wón mò ón télè)

Orin: Eni tá à ń wí, ó dé

Olówu Ògùdù, ó dé

Eni tá à ń wí, ó dé

Olùgbàlà wa, ó dé

(Ní wéréwéré, ijó ti bèrè, erukutu ń so làù. Ó sé, wón tún yí ìlù àti orin padà. Wón ń sáré lu ìlú bí i wí pé ìdúrò kò sí, ìbèrè kò sí)

Olówu ló wòlú, e fara balè

Olówu ló wòlú, e fara balè

(Eni tí wón ń ko orin fún náà sòrò)

Olówu: Olùbo ò ò ò ò

Olùbo: Olówu ò ò ò ò (Àwon méjèèjì gba owó ológun kí Olówu tó mórin sénu)

Olówu: Iná Mògún jó rire ò

Àrìsikà

Ìná Mògún jó rire ò

(Lóòótó, òsán ni wón ń se ìbo Mògún yìí, síbè, wón fi iná sí ògùsò)

Àwon Olùsìn: Iná Mògún jó rire ò

Àrìsìkà

Ínà Mògún jó rire ò

Àrìsìkà

Olówu: Ká jà ká bó lówó olòtè

Ká jà ká gbara wa lówó amèyà

Àwon Olùsìn: Iná Mògún jó rire ò

Àrìsìkà

Iná Mògún jó rire o

(Olówu tún pa orin dà )

Olówu: Ye ye ye, màrìwò ye molè

Mo méye rúbo

Àwon Olùsìn: Ye ye ye, màrìwò ye molè, ye ye

Olùbo: (Ó tún yí orin padà)

Àwá dé, àwá dé, àwá dé Onímògún o,

Àwá dé ò e e.

Àwon Olùsìn: Àwá dé, àwá dé, àwá dé Onímògún ò, àwá dé ò e e.

Olùbo: (Ó dáwó ijó dúró) Ó tó

(Ó sún mó ìdí ìbo) Lójú Olókun, a kì í fìyà jomo Olókun. Lójú yèmi dèrègbè, a kì í fìyà jeja nínú omi. Onímògún gbó, onílé orókè yéye. Ìwo lòpómúléró, igi léyìn gbogbo Ògùdù. Njé tá a bá sè ó, má fi bi wá, àwon eye tó su wá ni kó o so fún kí wón so fún wa. (O tún da obì, obì yàn, inú rè dùn, ó fi orin bé e). Mògún yèè.

Àwon Olùsìn: Yèè

Olùbo: Yèé a wí, Mògún mò gbó ò, Akin-òrun

Àwon Olùsìn: Yèé a wí, Mògún mò gbó o, Akin-òrun (Ayò abara tín-ń-tín. Ibi tí àwon ènìyàn ti ń jó tí wón ń yò yìí ni àwon olópàá ti ya wo inú agbo tí wón bèrè sí ní í da agbo wón rú. Ìgbà tí wón rí Olówu ni wón mú òdò rè pòn)

Àwon Olùsìn: (Wón ń pariwo nígbà tí olópàá ń nà wón) Mo gbé o, e gbà mí o, ìhà mí dá o, àyà mí fò lo ò, èjìká mi ti ye o, mo fó lórí o. (Wéré, gbogbo wón ti fi aré bé e. Omodé kì í sáà rí èrù kí èrù má bà á. O wá ku Olówu àti àwon olópàá nìkan).

Ògá Olópàá: Wón ń wá o lágòó wa

Olówu: Àwon taa ni?

Olópàá kan: Nígbà tó o bá dé òhún.

Olówu: Kí ni wón ní mo se?

Olópàá kan: Sé ìwo yóò tile sì dé òhún ná

Olówu: Ìwé tí e fi wá mú mi dà?

Ògá Olópàá: Òun nì yí (Ó fi ìwé hàn án)

(Olówu jòwó ara rè fún won láti mú lo. Bí wón se ń lo ni iná ń kú díèdíè títí tí wón fi fi orí ìtàgé sílé, iná sì kú tán pátá).

[edit] ÌRAN KEJÌ

(NÍSÒ ONÍGBÀJÁMÒ)

(Gbajúmò tó ń se gbàjámò yìí ń fi àkísà kan nu àwon irinsé rè, ó sì ń fi orin kan dá ara rè ní ara yá)

Gbajúmò: Ilè rúbo póun fé lékè ayé, òrò di pèé, wón téní lé e

Èní rúbo póun fé lékè ayé, òró di gbìrìgìdì, ìté oba lórí ení.

Ìté oba rúbo póun fé lékè ayé, òró di pèmù, ìdí oba lórí ìté.

Obá rúbo póun fé lékè ayé, òró di tepé, adé lórí oba

Adé rúbo póun fé lékè ayé, òró di té, esinsin lórí adé

Esinsin rúbo póun fé lékè ayé, òró di fìn-ín, alántakùn fún un pa

Alántakùn rúbo póun fé lékè ayé, òró di rìyèrìyè, atégùn gbò ó pa

Èmí láféfé ló tó lékè ayé tó o bá tó, o jà mí níyàn

Aféfé ni máyégún, òun ló ń máyé deniIórùn (Ó gbó ìró enìkan lénu ònà)

Ìwo ta ni o?

Jímó-òn: E pèlé níbí o.

Gbajúmò: E máa wolè o. Áh ah áh, kí ló dé tí e kò sì dúró fún òjò yìí tí aso yín fi tutù jìnnìjinni báyìí?

Jímó-òn: E è, e ò máa dára le ní ti yin. Ó ti tó ojó méta tí mo ti ń gbé e kí n lè wá fá irun mi, òjò yìí náà ni. Òní ni mo wá rò ó pò pé ohun tí yóò gbà ni yóò gbà, mo gbódò fá irun yìí lónìí ni mo se ti orí bo òjò wábí. Àbí o ti rí i sí, kíná máà kó wo eni náà nírun? Wón ní bó o bá rí eni tí irun rè kún yàwìrì, ti kò bá se Dàda tàbí Wòlíì, yóò se wèrè, èmi è é sì í se òkankan nínú won.

Gbajúmò: Òótó mà ni. Òjò òhún kò tile se, kò wò mó

Jímó-òn: (Ó ń jókòó sí ibi tí yóò ti fá irun) Òjò òhún bù di omi-yalé tán. Èmi ò tile fi owó ra eran mó báyìí, eja ni mo ń je. Eja òòjó, eja òfóòrò. Sé kò sí ojú àgbàrá kan sàn-án nílè yìí.

Gbajúmò: Béè ni, béè ni. Ó ń dà ó láàmú?

Jímó-òn: Rárá o. Bí mo ti ń pà eja ní yààrà ni mo ń pa lóòdè. Mo pa léyìnkùnlé dánwó, mo tún pa nítàa. Ti inú ògòdò gan-an ló dún jù. Ta ní ó so pómi ó má yalé? E jómi ó yalé, kó bùn à léja je. Ire ń be nínú ibi tó ò bá mò.

Gbajúmò: (Ó ń pón abe ìfárí) Ilé tí omi yóò wáá wó àti aso tí yóò gbé lo àti àwon erù gbogbo tí yóò bàjé ń kó?

Jímó-òn: Bílé wó, àgunla ilé, n kò kólé, mèháyà ni mí. Bó káso lo, àguntètè rè, n kò ní ju ti orùn mi yìí lo. Aso ara awó, aso bánbákú ni. Bó sì se erù èwè, kàn mí dà nínú òkú ìyá Àdèlé? Ohun tí òjò lè mú lo tó lè dùn mí kò ju èmí mi ló. Gàmbàrí kò níhun méjì ju ràkunmí. Oun ni mo mò pé mo ní. Sùgbón àwon nnkan yòókù, ikú wolé awó sákálá ni, eni tí kò níyàwó, àna rè è é kú,

Gbajúmò: (Ó dá owó irun tó ń fá dúró, ó ń wo Jímó-òn pèlú ìyanu) Ìwo ò níyàwó ni? O ò bímo?

Jímó-òn: Kò sí èyí tí mo ní nínú gbogbo won. N kò lébi, n kò lárá. Emi kò sí ní ara eni tí í kú tí à á sunkún sunkún, tá àá sòfò sòfò. Bi mo kú, ma kú bí aáyán, ma rà bí ìdin, kílè jo máa ru gbogbo wa lo.

Gbajúmò: Ìwo nìkan kó, gbogbo wa ni. Gbogbo dúdú tó wà nílè yìí ni. Ìlú won ni wón ti wa ń fìyà je wá. Adìye nìkan ni mo rò pé Olórun dá ní ìràbàbà àsádì, n kò mò pé ìsèèyàn nìseranko n náà nìseye. Ewo ni ká rò? Mélòó la ó kà nínú eyín adípèlé? Ti baba wa tí wón kó lérú ni àbí ti wa tí wón gbalè lówó è? (Ó bèrè sí níí fá irun lo, síbè, won kò síwó ejó)

Jímó-òn: (Ní ìdoríkodò níbi tí Gbajúmò ti ń bá a fá irun) O tún jé kí n fi àwon ènìyàn àtijó se ìrántí, tí wón gúnyán sílé fún wa tí wón fobè tó dùn ti í, tí wón la ònà tá à ń tò, síbè wón kó won lérú. Kò sí ibi tí a ti rí òpò ìjìyà tí ekún àti ìpayín keke gbé kóra jo bíi tinú okò erú.

Gbajúmò: (Ó dáwó irun fífá dúró, ó fi owó osì nu irun tí ó wà lára abe kúrò, ó sì fi abe ha owó díè kí ó lè mú sí i) O wí béè? Iyen kò tile dùn mí bí ilè wa tí wón gbà. Wón ra díè, wón fi díè gba pààrò, wón fi agídí gba ìyókù. Olórun ń be sá, adákédájó, bí béè ló bá dára.

Jímó-òn: Hè è, wón ti gbàgbé ni pé òbìrí layé, ń se layé ń yí, kò dúró denìkan, kò sì ní í pé kò ní í jìnà tí ayé yóò ko ibi tó dára sí òdò wa tí idà yóò fi orùn apani selé. Sùgbón tá a bá ní ká ro dídùn ifòn, a ó hora kojá eegun. O ò jé ká wá nnkan míràn so kí a dá inú ara wa dùn kí eni náà má lo ronú kú nítorí bá ò kú, ìse ò tán.

Gbajúmò: Òdodo mà ni. Ó tile jé kí n rántí enì kan tó wá bá mi lálejò. Sé ìyàwó métà ni mo ní, òrò ìyàwó náà ni òun náà sì ń so. Ó ń wàásù, ó ń sìpè péyàwó kan soso ló dáa kó wà loode oko. Ó se, ìyàwó mi kan gbé oúnje wá, a jo je é. Ìyàwó kejì àti èketa tún gbé ti won wá, okùnrin yìí tún fé bá mi je lára àwon oúnje yìí, mo yára mú un lówó, mo ní ìyàwó kan ló tònà.

Jímó-òn: (Ó ń rérìn-ín) Èmi náà se nnkan tó jo béè ní ojó kan. Sé àpèmóraeni là ń pe tèmídire. Kò sí eni tí a lè gbé okó fún tí kò ní í ro oko sí òdò ara rè àbí bí ènìyàn ko fìlà fún were, kò ní í lò ó gbó? Yóò lò ó gbó mònà. Oko etílé ni èmì àti òré mi kan lo ní ojó kan tí a pa igún méjì àti àróbò mejì. Ó ní báwo lá o se pín in? Mó ní ó lè mù igún méjì kí èmi mú àróbò méjì tàbí kí èmi mú àróbó méjì kí òun mú igún méjì, méjì kì í sáàá ju méjì. N gbó kí ni o rí so sí i?

Gbajúmò: Ìyen ò tilè dùn ó bíi wàhálà tí omo kan kó mi sí ní ojó kan. Wón pò tí wón kó bàtà sí inú oòrùn ní ojóún lóùn-ún, níwájú mi yìí náà ni. Ó wa se, léyìn ìgbà tí wón ti se eré tán tí oníkálukú ń kó bàtà tire ni omo yii wá ni òun kò rí tòun, ó ní òkan tó kù sílè kì í se tòun. Kí n má sì wá di bàbá onígbàjámò akóbàtà ni mo bá ń ba wá a. Léyìn òpò ìdààmú, mo bi í bí tìrè se rí. Párá tí omo yóò dáhùn, ó ní òrí wà ní ara bàtà òun nígbà tí òun bó o sí inú òòrùn ni òwúrò yìí. Àbí o ò rí omo akóni sí wàhálà, ó kó bàtà sí òòrùn láti òwùrò pèlú òrí nínú, kò mò pé yóò ti yó. Àsé tire ni bàtà tí ó wà ní ìta ti o … (Ó dákè nígbà tí enì kan sáré wolé lójiji, ó dáwó irun fífá ró àti olùfárun àti eni tí à n fárun fún ló jo woke) Sé kò sí ?

Làmídì: (Ó ń mí helehele) Ó sí o, ó sí gan-an ní, ó tile wà pèlú. Nnkan tí ó sonù nínú Mosálásí kojá sálúbàta torí odidi lèmómù la fi sàwátì, nnkan ti se.

Gbajúmò: Emi náà mò pé bí kò ní idí obìnrin kì í jé Kúmólú. Bí a bá rí àgbàlagbà tó dédé ń sáré làgbálàgbá, bí kò bá lé nnkan, a jé pé nnkan ń lé e. Kí ni ó dé gan-an? Kí ni ó selè?

Jímó-òn: Nnkan tí wón ti kó bù fún Ògun ni wón tún wá bù fún Òsanyìn, nnkan ti se. Wón ti mú ohun tí kò ye dé idí èsù, àbí o kò rí arákùnrin yìí bó se ń gbòn ni bí imò tí atégùn ń dà láàmú.

Làmídì: Ilè yìí ni o. Òde ò dùn, tálíkà ò gbodò lo òde emu mó o. Ó ti sú mi ò. Kò seé gbé mó o. Nnkan ò dára ò.

Gbajúmò: Kí ló tilè dé gan-an? Tí a bá sáà ń se é, ilé ayé ló ń gbé, òrun ni ohun tí a kì í se wà. Sé bí okùnrin ni ó, o kì í se obìnrin. Obìnrin ló máa ń fòrò falè bí eléyìí.

Làmídì: Sé e mò pé òní ni odún Mògún?

Gbajúmò: Hen en en, béè ni. Òní ni odún Mògún òkè ojà. Mo ní kí n se isé yìí tán náà ni kí èmi náà wá múra ojú ìbo.

Jímó-òn: Irun tí èmi náà fé gbé lo ni mo ń fá yìí. Ìmòle ò ní ká má sorò ilé eni bí àsá òré mi kan tó fi iléyá jé Ràsákì, tó fi kérésì di Lórénsì, tódún Ògún dé tó di Ògúnbùnmi, ó fodún eégún jé Òjéwùmí, ó …

Làmídì: Ìyen náà tó, àbí kí ni a ń wí kí ni e ń so? Bó se wu ènìyàn ló ń se ìmòle rè. Ení wù lè fi itan elédè je sààrì. Àní ibi tí e ń lo ti dàrú.

Gbajúmò: Dàrú kè? (pèlú ìyanu). Ta ló dà á rú? Mògún se tán tí yóò fi orí olúwa rè fon fèrè.

Jímó-òn: Bó forí rè fon fèrè náà ni kò burú. Àtòrundórun eni náà kò níí kúure láé

Làmídì: Àwon olópàá mà ni ò. Béè a sì da obì, obì sì fore. Àsé, Ààré ló ń pè wá tí a ń dífá. Ifá fore, Ààré fobi. Àwon olópàá tótó fùn-ún-ùn.

Gbajúmò àti Jímó-òn: (Léèkan náà) Olópàá kè? Dúdú àbí funfun ?

Làmídì: Owó ara wa la mà fi ń se ara wa ò. Dúdú mà ni ò. Dúdú ló ń fojú dúdú rí màbo.

Gbajúmò: Kí ni wón ló dé? Làmídì: Olówu ni wón wá mú tí wón fi lílù sé àwa yòókù léegun (Ò sèsè wá ń tè yéké bí ìgbá pé nnkan ńlá kan ti bà á lésè télè)

Jímó-òn: Olówu? Sé òré gbogbo wa?

Làmídì: Ìwo náà mò ón?

Jímó-òn: Ta ni kò níí mò ón? Kí ni wón tún ló se?

Làmídì: N kò mo ohun tó se gan-an sùgbón ó ye kí o mò pé òtá òrun ò gbebo ni Olówu àti ìjoba fúnra rè láìtilè so tì àwon olópàá. Èkúté kò sá lè san gbèsè ológbò tán láéláé.

Jímó-òn: Sé wón rí í mú?

Làmídì: Won ò se ní í rí i mú. Wón ní kí ènìyàn méjo lo mú o wá, o ló ò lo, lójúu wíwó, àbí kí ni ènìyàn kan yóò só pé òun gbé lé orí tí ènìyàn méjo yóò sò ó tì?

Gbajúmò: Wón tí mú un lo báyìí?

Làmídì: Pátápátá

Gbajúmò: Sé ilé lo n lo kí ń wá wo àlàáfíà re tí mo bá se tán?

Làmídì: Ilé kè? Èmi ni wón mà ní kí n lo fi òrò náà tó aya Olówu létí.

Jímó-òn: Kò tí ì gbó?

Làmídì: Kò tí ì gbó

Gbajúmò: Kúkú dúró kí n se tán ká jo lo. Oré tàgbà tèwe ni Olówu. Ènìyàn kò gbodò fi òrò rè falè. Òkà rè sòro í ko kéré.

Jímó-òn: Èmi náà á bá yín débè. Olówu kì í jé béè.

Làmídì: E mà se é. E jé kémi náà jókòó kí n máa sinmi títí tí e ó fi se tán. Eni tó ń fi tirè sílè tó ń gbó teni eléni, Olórun ló ń bá a gbó tire (Ó se, wón se tán. Wón mú ilé Olówu pòn. Wón daso bo ìtàgé).

[edit] ÌRAN KÉÈTA

(NÍLÉ OLÓWU)

(Bí wón ti tan iná, àwon omodé méjì kan la rí, obìnrin sì ni àwon méjèèjì. Omo Olówu ni wón, Eré ni wón ń se, won kò kúkú mo ohun tó ti selè)

Sílífá: Kí ni hewú?

Àdùké: He

Sílífá: Àdán hewú

Àdùké: He

Sílífá: Kólé osó

Àdùké: He

Sílífá: Tèpá òòjé

Àdùké: He

Sílífá: Gbègbè hé ń mì

Àdùké: Héè

Sílífá: Gbègbè hé ń mì

Àdùké: Héè (Wón gbó ko ko ko lára ilèkùn, Àdùké sì lo sílèkùn fún eni náà. Ó rí àwon okùnrin méta, ó kúnlè kí won) Ta ni e bèèrè?

Làmídì: Àwon màmá e ni

Àdùké: Wón wà ní yàrá. E wolé ké e jókòó kí n lo pè wón wá (Wón wolé, wón jókòó sí orí ìjókòó tìmùtìmù tí ó wà ńlè. Sílífá àti Àdùké ló pe màmá fún won láti yàrá)

Làmídì: Olówu mà ná owó si ilé yìí o (Ó ń wò yíká). Ajé kú ìjokòó. Se ni ìjókòó yìí se mí fìn-ìn-ìn.

Gbajúmò: Kò se níí náwó sí i, o ò moye ìwé tó kà ni? Odidi dókítà níní isé lóóyà.

Làmídì: Òótó mà ni, ògbólógbòó lóóyà tó mòye. (Rónké, aya Olówu wolé, gbogbo wón sì dáké, kíkí ni Rónké náà fèrè fi ba tiwon jé)

Rónké: A mà rí i yín

Làmídì, Jímó-òn, àti Gbajúmò: Béè ni

Rónké: E pèlé, e nlé, e kú ojó, e kú òtútù, e kúu bí yóò se dáa, aya ń kó? Omo ń kó? Gbogbo ilé ń kó? àlàáfíà kí wón wà bí ..?(Àwon náà ń dá a lóhùn. Kì í se pé Rónké mò wón dunjú sùgbón òyàyà pò, àyésí èyí tóyìnbó ń pè ní yèésì kùn owó rè. Tonílé tàlejò ni ó máa ń yé sí. Kò sì fi ti pé ènìyàn kàwé kún un rárá. Bí ó ti ń kúnlè ni yóò máà bèrè tí yóò máa ga láti lè fi ìbòwò-fún hàn).

Làmídì, Jímó-òn àti Gbajúmò: A dúpé, e se é o, ò o, yeesì mà … (Wón dáhùn lo kánrin, kò sí bó se jé ni)

Rónké: Sé kì í se pé ó sí nnkan o? (Ara ń sòrò fún un. Sé kò rí won béè rí) Sílífá!

Sílífá: Ma, mo ń bò mà.

Làmídì: Kò sí mà, kó má bàa sí náà la se wá (Sílífá wolé, Rónké sì so òrò kélékélé sí i létí, ó tún jáde padà)

Rónké: Kí wá ni gan-an-an?

Làmídì: Ibi tí a ti ń bo Mògún lówó ni nnkan ti se

Rónké: Oko mi mà lo kè. Sé kì í se òun ni nnkan selè sí? Kó má se ara mi nisó ti ń rùn. Mo sì so fún un o. Ti ìjoba amèyà ni ó tile wà lókàn mi nígbà náà wí pé eni tí a kò fé ní ìlú kì í dárin, ení fi epo ra ara kì í sún mó iná, n kò tilè mò nígbà náà pé nnkan yóò se ní ìdí Mògún. (Sílífá wolé pèlú kiní kan tí a dé mó abó olómi góòlù kan lówó. Ìyá rè gba abó náà ní owó rè, nígbà tí ó sí i ni a rí i pé obì ló wà ní ibè) E dákun, e bá wa fi owó bà á o.

Gbajúmò: (Ó gbà á) E mà se é o, e kú ìnáwó, a dúpé gan-an.

Làmídì: Ibi tí a ti ń bo Mògún lówó ni àwon olópàá ti wá mú oko yín.

Rónké: (Ara rè bù máso) Mímú kè? Kí ni wón ló se?

Làmídì: Kò mà yé wa o. Se ni wón dédé dé tí wón da agbo ìbo rú o. Kí won tó se èyí, wón tile férè fi lílù dá nnkan sí wa lára ná. Wón férè lù wá sé léyìn. Gbogbo ìmumi ló ń ro mí báyìí. Nnkan tí a máa rí ni òdò oko yín tí wón lo tí wón fi ìwé lé e lówó pé kí ó tèlè àwon.

Rónké: Wón sá ti mú un lo báyìí? Sé kì í se torí pé ó se nnkan kan ní ibè tó lòdì sí òfin?

Làmídì: Rárá o. Jéé ni ó ń se. Sé àwa là ń rí i kò lè rí ara rè, abí, ìpàkó onípàkò kó ni à ń rí ni tí eni eléni ń bá ni rí teni, onígbàjámò kò sá lè fárí ara rè. Bí ó se jé àtùpà tó tí ó ń mú gbogbo aráyé ríran, síbè, kò lè rí ìdí ara rè. Àwa tí a rí won ni a mò pé pèlépèlé ni wón máa ń se.

Rónké: Èmi náà mò, mo kàn ní kí n tún bèèrè ni. Mo sá mo ìwà ará ilé mi kì í se èébú. Mo mo ohun tí baálé mi lè se nípa èsìn. Àwon méjì témi mò pé kò wùùyàn nípa èsìn ni wèrè tó ní kò sÓlórun àti olòsì tó gba wèrè mésìn. Oko mi kìí sìí se òkankan nínú méjèèjì yìí.

Jímó-òn: Béè ni, béè ní, òré òré eni, òré eni náà sáà ni, Olówu è é sòré mi gan-an sùgbón òré òré mi ni. Àwòdì òkè kò sì mò pé enì kan ń wo òun ni òrò yìí. Gbogbo wa la mò bí Olówu se rí. Kò sebi séèyàn rí. Kó-dára-fún-gbogbo-wa náà ló ń bá kiri, ká-yo-lówó-àwon eléyàmèyà ló je é lógún.

Gbajúmò: Òótó ni, òótó ni, oko yín kò se nnkan kan tó burú rárá. Òrò sùn-nù-kùn, n se ni ki e jé kí á fi ojú sùn-nùkùn wò ó. Òtá òrun ò gbebo lòtá àsádì òun adìe. Bígi gbómi lógún odún, kò lè dòònì láéláé. Àrá ò lè se bí ìjì, mònàmóná kò sì níí fi ìgbà kan se bí òjò. Ìjoba eléyàmèyà kò lè fìgbà kan féràn oko yín torí ìjà àjàgbara tó ń já fún wa.

Làmídì: O wí béè?. Sùgbón, ó sì le ni, olópò èrò ni ogun yóò sé fún lójókójó. A ó ségun òtá, a ó réyìn odì, lágbára Òrànfè.

Rónké: Mo dúpé (Ojú rè ti ń pón). Mo dúpé gan-an ni. Sé wón ní eku níí se elérìí eku, eye níí se elérìí eye. E se é gan-an ni. Ni ojó tí oko mi ti gbà láti jà fún dúdú ni mo ti mò pé isé gidi ló gbà. Sùgbón mo sì rí bàbá Àdùké náà bá wí sá. Eni ejò bù je rí, kí ó sá fún alángbá ni mònà . Nnkan tó sá se ni rí nì yí, ó ye kí ó yera fún un.

Jímó-òn: Béè ni. Sùgbón Olórun kúkú ń be léyìn olódodo. Teni ó dé la rí tá à ń so yìí, ta ló lè so tenì tó ń bò? Bí kò sí ihò tó wà nítòsí, èkúté kò lè yájú sólógbò. Àwon ìlú ńlá tí ó wà léyìn àwon eléyàmèyà yìí ló jé ki won máa se bí wón se tó.

Rónké: (Tí a bá ti so òrò iyì nípa oko rè, inú rè máa ń dùn wí pé wón mo rírì ohun tí ó ń se) N kò mo ohun tí ó kan lèmómù nípa itan ajá, okò òfurufú kò sá ní nnkan se pèlú pé gádà já. Bí kì í bá se ajunilo ti í fi owó eni gbáni lénu, kí ni ó kan aláròóò nílèe wa? Kí ni ó fa funfun délèe dúdú? Ìkojá àyè, oorun orí kèké.

Jímó-òn: Fi wón sílè. Òkìtì òbo ni wón sì ń ta lówó, bí wón bá wo ekù tán, won yóò wá wo káábíyèsí.

Rónké: Nnkan tí mo máa ń so fún Olówu náà nù-un pé a kì í mowó ilè eni kó kú ni nísu pé kí ó sì máa se pèlépèlé ná torí àwon afé-á-je-má-fé-á-yó tí í fún ni lóko lábé òpe.

Jímó-òn: E má so béè o. N kò rí nnkan kan tí wón se tó jura lo báyìí. N kò rò pé nnkan tí ó ye ni kí a lé onílè kúrò ní orí ilè rè. Òrò ti wí pé a bá erán wí ó ye kí á bá eràn wí kó ni eléyìí, bí òrò bá se rí ni kí á so ó, Olówu kò jèbi páà, ònà tí a ó fi gbà á sílè ni ká mú pòn báyìí.

Rónké: N ó lo bá agbejórò rè, ìyen Músá, láti mo èyí tí a ó se. Bí sòbìyà bá sá se bí eré degbò, mo se bí olúgànbe là á ké sí.

Gbajúmò: Ko burú (Àwon métèèta dìde láti máa lo): A ó tún máa wá wò yín. (Wón jáde, Rónké sì pé wón lésè díè kí ó tó padà)

Rónké: (Ó ń dá sòrò) N ó kúkú mú ònà pòn báyìí náà. Bísé kò péni, a kì í pésé, ká gbá ni léti, ká fi ekún bé e ni. Wón ní bó bá ti yá kì í tún pé mó, àlè oníyèrì (Ó sòrò sókè) Àdùké

Àdùké: Mà

Rónké: Mú gèlè mi wá kí o sì bá mi mú ìborùn náà. N ó kúkú se é ní kóyá. Jé n kúkú pa bàtà eléyìí náà mésè péé-pèè-péé béè; kì í kúkú se òde ni mo ń lo.

Àdùké: (Ó kó won dé) Àwon ni yí màámi

Rónké: O káre (Ó ń múra.) Kíwo àtègbón re mójú tólé o. Mo ń bò o (Ó jáde, Àdùké wolé lo) (Iná kú)

[edit] ÌRAN KÉÈRIN

(NÍLÉ LÓÓYÀ)

(A rí omodékùnrin kan tí ó ń to àwon ìwé bànbà bànbà kan báyìí sí orí tábìlì. Ó joun pé òun ni akòwe lóóyà. Ní apá òsì ni obìnrin kan jókòó sí tí ó ń te ìwé pe pe pe. Rónké kan ilèkùn ko, ko, ko).

Rónké: Àgò onílé o.

Àlàdé: (Omodékùnrin yen) Olórun ló ni ín o

Rónké: E káàsán, e pèlé

Àlàdé: Yeesì mà

Rónké: Arábìnrin, e mà kú isé

Sèyí: Àwa nì yen mà, e se é púpò

Rónké: Àwon ògá wa wá ń kó?

Àlàdé: Wón wà ní sénbà. E jé kí n bá yín pè wón wá (Ó wolé lo pe ògá rè wá, kò pé náà tí Músá fi yojú sí òde)

Músá: Àh, Màdámú, èyin ni, e pèlé, e kú ojó méta kan. E wá jókòó síbí.

Rónké: Àwa mà nìyen o, e se é púpò, e kú isé.

Músá: Àwon ògá Olówu wa ń kó?. Olówu fúnra rè. Sèkèrè ò se é fòpá lù, alágbára ò se é fara wé. Òkansoso òsùpá tí kì í segbé egbèrun ìràwò. Sé kò sí tá a rí yín o?

Rónké: Kò sí púpò, kó má baà sí náà ni. Òrò oko mi náà ni mo bá wá. Àwon olópàá mà tún ti mú un.

Músá: Mímù kè? Kí ni wón tún ní ó se?

Rónké: Kò mà yé mi o. Àrà tó wù wón ni wón mà ń dá o. Onírúurú ìgèrè lówó akódò won ló mà wà o. Ibi ìbo Mògún ni wón tún gbà yo lótèyí o.

Músá: Won kò so nnkan kan tó se rárá?

Rónké: N ó máa tàn yín bí? Wón kò so nnkan kan. Àgbin sínú lerin won gbin. Ìsàlè ikùn ni wón fi òrò hùn-ùn-hùn-ùn inú elédè won sí. Won ko so ohun páà fún enì kan. Òdú kì í sáà sàlejò olóko. Òní kó ni wón ti ń se béè mú un.

Músá: Kò burú. Bí èyí tá à se bá tán, èyí tí a kì í se náà kó má jáfara. Sé wón ti gba béèlì rè?

Rónké: Gbígbà kè? Òhun náà ni ó mú mi wá síbí.

Músá: Kò burú, e máa lo sílé. Tenu eni ló fé gbó, èkúté tó fi àkò sílè tó ń jòbe. Fífà náà la ó bá won fà á. Bí se ni wón bá rán won sí wa ni kí won tètè lo jísé padà pé won kò bá wa nílé tàbí kí won so pé àwon kò lè dá isé jé nítorí adìye tó bà lókùn ni òrò yìí, ara kò ní í ro okùn, ìdèrùn kò sì ní í sí fádìe. Omo tó ní ki ìyá òun má sùn, òun pàápàá kò ní í séjú péé. Mo ń lo bá won báyìí lágòó won. Odì kò sá jìnà sílé oko.

Rónké: E mà se é o. Òrò mi tilè sú mi báyìí. E ò se jé á kúkú jo lo? Ara mi tile sì ń gbòn.

Músá: E má sèyonu. E jé kémi won jo lo yan wèrè pò lóhùn-ún. Èèyàn kò sá lè se ju eléyìí tí Olówu se yen ló. Kó dára, kó dára sá náà ni. Asín torí ìwòsí, ó gbé enu rè ní kàfó. A torí ká má jìyà yá májìyà lófà, wón tún ń fìwòsí lo asín wón ń fìyàá lò wá. Èyin e sì fi wón fún mi, e fi wón sílè, e fèjè sínù ná ké e fitó se funfun sita, kí e sì jé kí òógùn arà adìye yín sì wà lábé ìyé ná, kí èmi àti àwon lo fi òfin dà á rú lóhùn-ún, òrò ò tì ì di ti gbogbo gbòòò.

Rónké: N kò tilè mo bémi se yan orí sá. Èmi nìkan sá lójoojúmó bí ekún apokoje. Njé gbà lónìí, gbà lóla, bí ojú kò tilè fó, kò níí di ràdàràdà? Ojoojúmó, èwòn, èwòn, èwòn nítorí ìjàgbara yìí náà ni. Ìdè lówó, ìdè lésè nígbà gbogbo, njé tó bá se pé esè ń run ni bí inú ni, se bí ìbá ti daro. Bí kò se pé ó ní okàn ni, ìbá ti kú séwòn. E dákun e bá mi se é o, e má jé ó wèwòn mó o.

Músá: Kò le tóyen Màdámú. Olówu kúrò ní ènìyàn yepere. Ènìyàn kì í sáà jé akérémodò lórí òkun eni. Ilè wa sá nì yí. Kò sí bí wón se lè se wón rárá. Bólógbò so pé òun yóò pa àkèré, tojú timú ni yóò tì bo omi. Olówu kò se í pa kò se í kàn lóògùn, yíyó rè ti ju bóróbóró lo, a ò ríhun pè é ni. Ń se ni wón ń bá awo jà, Sàngó ní ó ń se olówó sééré. Àbí ìwo rí ibi tí òjò iwájú ti pa ahun tí tèyin pàgbín rí? Ajá ni wón fé lò, òbo ni won yóò máa fowó rà wálé. Tálejò bá kò tí ò lo tí omi okà wá lo tiiri tí kò hó, kò parí? Sìsesìse èyí tó bá òbúko tó fi bá ìyá rè sùn. E sá máa lo, mo ń lo já bá won, torí wèrè òde la sá se ń ní wèrè ilé, e máa lo, mo ń bò wá fàbò jé yín. Òpin òròmo sá ladìe, òpin òwúrò lòsán, èyí náà la ó fi sòpin bóobòo tí won kò ní í fi mú Olówu mó, gbogbo ara ni n ó fi se é.

Rónké: E jé kí n bá yin lo kí n mójú gán-án-ní won.

Músá: Àní kí e máa padà sílé, kò lè sí nnkan kan. Nnkan kan kè? Kò tilè gbodò sí ni mònà. Láti ibo? Kò tilè gbodò ti owó won selè sí Olówu. Nnkan tí òfin fi lélé nìyen. Àwon náà sì mò ón, won kò jé jose. Ojú abe seé pónlá ni? Wón fé jiyán won nísu nìyen. Eyin adìye wón fé forí gbá okúta, ó fé túká yángá. Bí wón bá se ohun tí ó lòdì sí òfin péré, òkò ni wón so pa adìye yen, òkò tí won yóò so yóò ju igba lo. Adìye aláròyé ni wón gbé un, ìyen adìye òtòsì. Kèrè tí ilé fi ń mumi ni wón sonù-un tí won kò mò. A fún won sun ni, a kò ní kí won yan án jóná. Tí lèmómù won bá sì lo dákú ní ìdi Sàngó, tó bá jí, yóò sàlàyé. Tí nnkan kan bá se Olówu péré, won yóò tò, enu won yóò gùn gbooro.

Rónké: (Ó gbà láti padà sí ilé kí ó má bàa di alásejù) Kò burú o. Bó bá sì se jé, ké e jé n tètè résì o. Nnkan tí ó kàn ń bà mí lérù ni pé ti wón ti jóná ti wón ti bàjé. Eni tí tirè sì ti jóná, kò lè ní kí tomo elòmíìn má dètù. Eni tí tire ti bàjé, kò lè ní kí tomo elòmíìn má bàlùmò. Kí won sá dákun má bá mi se Olówu mi sìbásìbo.

Músá: Tí won ló bàjé, ti won ló jóná. Nílé ti won lóhùn-ún nù un, kò dé òdo ti wa níyìn-ín. Èèyàn ò sá rí ibi ti òsùká orí imò ti bá imò dè ilé rí, rárá, kò seé se. Omo ahun kì í to ahun léyìn, tejò náà kì í tòyá è. Won kò fi òrò orí fífó lo omo akàn rí. Àyúnlo àyúnbò bàyìí ni owó ń yénu. Láyò ni Olowu yóò lo, láyò ni yóò bò lágbára Obalúayé. Ojú àlá burúkú ni kí á fi wo òrò yìí fún Olówu. Alá burúkú kì í sì í gbéni dè sórun. Àpárá ni eye ń dá tó so póun yóò rí omi inú àgbon bù mu. Won kò lè fi Olówu sehun páà. Bí wón lé e, won kò ní í bá a. Bí wóń bá a, won kò ní í rí i mu, Bí wón rí i mú, won kò ní í lè fi se nnkan kan lágbára Èlà ìwòrì atáyéro.

Rónké: Kò burú o. N ó so pé e wí béè o. E jé kí n máà lo sílé láti lo mójú táwon omo.

Músá: Kí won fún mi o. Rere letí yóò gbó o. Ó dìgbà. (Rónké jáde, Músá ń bá àwon akòwe rè sòrò) Mo mà ń ki obìnrin yen láyà ni o torì n kò mo ohun tí n ó bá lóhùn-ún. Ń se ni a wú láyà lásán tí mo so pé a gúnmú. Sèyí: Le sì ń sòrò bí ìgbà pé kò sí nnkan kan.

Músá: Ara nnkan tí mo máa ń so fún yín nípa isé wa yìí nìyen. Bí a ń wo ikú lójú báyìí, a gbódò máa so pé kò sémìkémì. Nnkan tá a kó mósé nù-un. Nípa ti Olówu yìí, méwàá pàápàá wà. Ayé ti bàjé, a kò mo ibi tí ìjoba eléyàmèyà yìí lè gbà yo sí wa. A kò sá ní í sàìfi ìyànjú se gbígba sá. Ìwé kan tí mo kà lára ìwé tí Olówu kó pamó sí òdò mi pàápàá ń ko mí lóminú (Ó kó won jáde). Ó ko èyí sí ìyàwó rè tí ó sèsè lo yìí (Ó ń kà á) “Obìnrin ni ó, obìnrin tó lágbára. Mo ní o wá mú mi lówó dáni, ìwo obìnrin olóòótó. Eni tí mo fokàn fé. Obìnrin nínú obìnrin, ayaba nínú ayaba. Obìnrin tíí sòsán dòru tíí sòru dòsán. Obìnrin tíí ro ìrora èéyàn. Obìnrin tíí mórí tó dàrú pé. Obìnrin tíi ròjò ìfé luni. Obìnrin tíí sèyá jelòmíìn lo bí baba omo ò tilè sí nílé. Mo ní bójú bá yejú, kóhùn má yehùn, tá a dá fún Wáwá, ode ayé. Àní bójú bá yejú, kóhùn má yehùn, tá a dá fún Gbúèdè, ode òrun. Obìnrin tí ó dára ni ewá oko rè, iwo lewà mi o, Rónké”. Hùn ùn ùn, ò sì ko èyí bí eni tí kò ní í pé kú …“Obìnrin tí ń sèyá jelòmíìn lo bí baba omo ò tile sí nílé…” Olórun má mà jé ká rí láburú o . Ojú mérin tó bímo ni kó wò ó o . (Ó tún mú ìwé kejì) Àwon ènìyàn ìlú ni ó ko èyí sí (Ó ń kà á ) “E dìdè, e jàjàgbara. Kò sí ohun tí yóò se yín ju okùn apá yín tí yóò já lo. Èrò ibi ni wón fi bo rere ti yín mólè, e dìde, e jàjàgbara. Okàn yín ń pariwo, tèmí ń ké, fún ìlú tí a fìyà je. Ó ti pé, ó ti jìnà, tí wón ti ń so pé àyípadà yóò wà, síbè, kò sí, kàkà kó sàn fún ìyá àjé, abo ló ń bí ti eye wá ń yí lu eye, ń se ni ohun gbogbo ń peléke sí í, kò rò. Kò sí gbogbo bí e ti se é tó, ibi pelebe ni òbe té e jù tún fi ń lélè. Àwa náà ni wòn yóò sì ló jèbi, èké ń rojó, èkè ń dá a. Eyin náà le ó jagun ìgbàlà fún ara yín, enì kan ò ní í ràn yín lówó torí owó ara eni la fi ń tún ìwà ara eni se. Bí ènìyàn yóò tilè ràn yín lówó, elérù níí kókó gbé e kí á tó bá a fi owó tì í. Èyin òdó, èyin èwe, èyin èsówéré, èyin le ó gbara yín, eni kan ò níí gbà yín. E dìde kí e ja ìjà àjàgbara. Àbí kí ni elémèso yín ń se nígbà ti baálé ilé ti fò sókè? Orí igi ló ye yín ó, té è bá mò”. À bé è rí nnkan? Ohùn tójú wa ń rí lÓgùdù nù-un o, lówó ìjoba amèyà.

Sèyí: Àwa le sèsè ń so fún. Ohun tí ojú àwa pàápàá ń rí ló ń jóun. Má su, má tò, òfin agbèsìn sódì. Ó ní ibi tí dúdú ń dé. Ó ní ibi tá a lè tè. Àwa là ń wa kùsà tó ń dowó fún won. Bí ajá sì peran wálé tan, ìjànjá ni yóò kàn án

Àlàdé: Ìyen tile dùn ó bí nómbà ti wón ní kí dúdú máa gbé kiri bí i teléwòn. Wón so wá derú nílè wa, Olórun yóò kúkú dá a. Sèyí: Okùnrin kan tile se kiní kan ní ojó kan tí ó wù mí wù mí.

Àlàdé: Kí ló se?

Sèyí: Ó wa kùsá tán ní ojó òún ni ògá isé wá so fún un pé kò se é tó. Ni okùnrin yìí dáhùn pé “Bí díè yìí kò bá ti té yín lórùn, a jé pé rárá fé ni e ń ko ìwé sí yen. Àbí, a kó ilé kóróbójó, wón lóòsà ò gbà á. Tí kò bá gbà á, kí ó lo igbó lo sáké, kí ó lo òdàn lo wókùn, kó rí i bágara ti ń dáni. Èyin náà, e fòbe dánrùn wò, kí e wo bó se rí kí e tó mò pé kò sí ohun tó dùn to àrùn ibà láti ojú orun dójú ikú. Eyin náà ìbá wo ihò ilè wò kí e rí i bí ó se rí.”

Àlàdé: Hen én, ó sò yen tán? Nílè yí náà? Ojú rè yóò rí mòbo.

Sèyí: Ó rí i, ó rí i. Òràn gan-an ni ó dá mó òràn fún nnkan tí ó so náà. Gègè ni ó ní télè tí ó tún lo je gbèsè, òràn wá di méjì lórùn. Àwon ìjoba amèyà kò sì gba irú rè láàyè. Wéré ni wón pa á. Nikú ogún wá pa akíkanjú tí ikú odò pòmùwè, ikú ewà wá se òkín nísé, ikú ara ríré wá rán ògé lo sórun, àgbàyewo wá sekú pa ìbon òyìnbó, “èmi ló dára tó yìí” wá sekú pomoge, ikú ìko ìwòsí ni ó pa okùnrin yìí, béè, báyìí gélé ni òrò Olówu rí ló jé kí èrù máa bà mí fún un.

Músá: N kò mò pé èyin náà fura. E jé n tètè lo sí àgó olópàá kí n wò bí òhún ti rí. Eyin náà lè pale mó, kí e lo so fún won ní kóòtù alágbádá pé n kò ní í lè wá, kí won sún ojó ejó tí a ní síwájú. (Ó jáde, àwon omo náà sì ń palè mó. Wón ń kó nnkan wolé ogba ni iná kú).

[edit] ÌRAN KARÙN-ÚN

(ILÉ BABALÁWO)


Rónké: (Ń dá sòrò). Eyí tí n ò fi lo sí ilé, bí n bá kúkú lo sódò arínúróde, akónilórò bí ìyekan eni, láti lo bèèrè bí nnkan yóò se rí ń kó? N kò kúkú mo dídá owó, n ò mo ètìtè ilè. N ó kúkú méèji àdìbò, n ó fi mééta ìténi kí n gbalé awo lo, lo wádìí òrò. Lóòótó, Músá ti so pé bí ó kúrò ní kàrì, àwon yóò fi kún kèdu síbè náà, ìkòkò ńlá kì í rá nnkan. N ó dè fún un níyìn-ín, n ó dè fún un lóhùn-ún, kéran má lo. (Bi babaláwo ti jí ní tirè, ìre ni ó ń sú, ìre àsodúnmódún, àsosùmósù, ìre fún owó, ìre fún isé òòjó)

Babaláwo: Òkànràn kan níhìn-ín, òkànràn kan lóhun-ún

Òkànràn ló di méjì, won a dire

A díá fún Sangó, níjó tó ní kíre gbogbo wá báun

Ni wón bá kó o ni dídá owó

Wón kó o ní titè ilè

Ni wón bá ń ní

Ojú aró kì í ríbi lóde òru

Tefun è é ríbi lóde òsán

Èyìn òkú là á fogbá òkú

Èyin rè là á jèkò rè

Ibi gbogbo ò ní í sojú re

Lájo, kódà tó o ó fi délé

Nítori tódún bá dun, gbogbo ìràwé oko

Won a kosin fúnlè

Màrìwò òpe kì í sì í bági oko wówé

Àkàlàmàgbò oko, láti ìgbà ìwásè

Kì í podún je

Àse mefà nìwo Òrúnmìlà kà

Méfèèfà la sì se

Lo sì ní á máa méyìí sohùn fò lójoojúmó

Wí pé isu atenumórò kì í jóná

Ogèdè rè kì í dè pòjò

Eni tí ò jéni gbádùn là á gbàlè fún

Ebè mi ré o ibi gbogbo bí ilé

Kó rí fún mi bí omo oba lóde Òyó

Tí wón ní ojà rè kò ní í kù tà

Tó se bí eré tó mórin sénu

Pé, e sáré wá rajà omo oba

E sáré wá rajà omo oba

Òpò ènìyàn ló ń rajà Èyíòwón

E sáré wá rajà omo oba

(Ká sòrò ènìyàn kò tó ká bá a béè. Orin awo ni babaláwo ń ko lówó tó fi gbó ko ko ko lára ilékùn)

Babaláwo: Ta ni o ?

Rónké: (Ó wolé) Èmi ni ò, e kú isé o

Babaláwo: Ò o, mò ń bò o (Ó parí èyí tó ń se lówó). Sé kò sí?

Rónké: Kò sí baba, mo wá wádìí nnkan ni

Babaláwo: O ò wa sòrò sówó o fi i síhìn-ín.

Rónké: (Ó sòrò sówó kélékélé, ó sì fi sí ibi tí a ní kí ó fi í sí)

Babaláwo: (Ó gbé òpèlè sánlè) Hen en èn o. Kí n wá yè ó lówó kan ìbò wò kórò di fà nlè. (Ó bèrè sí ifá dídá)

Òsán gangan awo òsán gangan

Kùtùkùtù awo àárò

Ifá ní níbo ni wón yí ota arò Ògún sí?

Wón ní nígbó ológbin ni

Agbòn Eléfúndáre ni wón fi di èru Ìgèdè kale

Wón pe igba omo eku jo

Wón ní ki won ó wá rù ú

Gbogbo omo eku sá lo

Ó wá ku Tòròfínní nìkan

Ó rù ú tán

Ó sò ó tán

Ewà ló dà fún un

Ni gbogbo omo eku bá pé jo fi jolórí won

(Ó dáwó dúró wo Rónké)

Hùn ùn ùn, olórí àwon kan ni ó wá bèèrè nnkan nípa rè?

Rónké: Béè ni

Babaláwo: Ó se isé ribiribi kan fún àwon wònyí ni wón se fé fi je olórí won?

Rónké: Béè ni

Babaláwo: O wá fé mo ipò tí òun gan-an wà?

Rónké: Béè ni

Babaláwo: (Ó tún gbé òpèlè sánlè)

Akéré finú sogbón

Òrúnmílà, asèkan-má-kù

Alukore ayé máa gbó

Alùyàndà Olódùmarè

Eni abé awón máa gbó o

Bí wón se ń wí bí wón bá ń lo rèé o

Wón á ní

Bótí bá kannú igbá

Oti a máa pani

Bóògùn bá pò lápòjù

A máa so ni di wèrè

Bá a bá lóba lánìíjù

Iwín ní í sín ni

Bóbìnrin bá gbón lágbòn-ón jù

Péńpé laso oko rè í mo

A dá fómo lÓgùdù mojò

Omo-a-kò-dúdú-lo-dààmú-funfun

Wón ní kó febo olà sílè

Ebo ajogun ni ó se

Èsù àìsébo...

(Ó tún dáké, ó wó Rónké)

E lo ye nnkan wò ní òdò awo kan ní ojósí, ó ní kí e se ebo kan, njé e se é?

Rónké: A ò ráyè se é, wón ń da oko mi láàmú nígbà náà. Wón lé e kúrò ní ìlú.

Babaláwo: Ìwo ò sì lè bá a se é tàbí kí òkan nínú ará ilé yín se é fún yín?

Rónké: Okàn mi kò tile lélè nígbà náà. Ìgbàgbó oníjo kiriyó sì ni àwon ará ilé wa. Wón láwon ò lè fowó kan nnkan òòsà. (Igbà tí Rónké ti so èyí ni Awó ti mò pé nnkan ti bó, ikú ni yóò kéyìn èwòn tí Olówu wà, sùgbón Awo kò so òótó kí ó lè rí tirè gbà lówó Rónké, òpèlè náà ni ó tún gbé sánlè tí ó ń fa irun iwájú pò mo tìpàkó nílé Ifá)

Babaláwo: Wútùwútù yáákí, wútùwútù yán-nbele

Owó ikú ní ń máa ń wá itóróró itóróró

Owó ikú a máa wà itòròrò itòròrò

Àwon eye kan abi ìfò sóró-sòrò-sóró

Ni wón se awo won ní ikòo kìíkú

Òrúnmìlà wá mú isu

Ó fi sú ikú lójú

Ó mú òkùnkùn

Ó fi kùn ún lójú bìrìbìrì

N ní ìjímèrè kì í se é kíkú igi bíbé

Tólógbò kì í se é kíkú ìwòsílè

Bórò se rí báyì, orin ló fi bé e.

Ló wá ní ogún odún òní

Òkè ń be láìkú gbon-in-gbon-in

Gbon-in-gbon-in ni tòkè, òkè, òkè gbon-in-gbon-in

Igba odún òní, òkè ń be láìkú gbon-in-gbon-in

Gbon-in-gbon-in ni tòkè, òkè, òkè gbon-in gbon-in.

(Ìgbà tí Awó ti sórò nípa “kìíkú” yìí ni ó ti mò pé òun ti pegedé)

Babaláwo: (O kojú sí Rónké) Fowó kanlè kó o fi kan oókan àyà re.

Rónké: (Ó se béè) Orí mi bá mi se é o. Àyà mi bá mi se é o. Òrúnmìlà dákun gbà mí o.

Babaláwo: Ikú ti yè lórí awo, àrún yè lórí è pèlú nítorí èté awo lèté awo, èté ògbèrì lèté ògbèrì. Eni tó o wá bèèrè òrò nípa rè ti joyè kòkúmó. Bó bá sì fi kú péré sí ibi tí ó wà, àwon tí ó wà ní sàkání rè dáràn nù-un. Idúró kò sí, ìbèrè kò sí, torí, odó ni wón gbé mì.

Rónké: E se é baba, èwo wá ni síse báyìí? Kí ni ohun ebo òtè yíí?

Babaláwo: Àwon ohun ebo pò gan-an ni sùgbón ó pon dandan kí e se é, Àwon náà ní: Eku méji Olúwéré

Eja méjì abìwè gbàdà

Òbídìe méjì abèdò lùkélùké

Ewúré méjì abàmú rederede

Erinlá méjì tó fìwo sòsùká

Àteyelé méjì abìfò gàngà

Rónké: Sé ó tán?

Babaláwo: Ó pari. Tó o bá ti gbó rírú ebo báyìí tó o rú. Tó o gbó èrù àtùkèsù tó o tù. Àní tó o bá ti gbó tí òkarara ebó ha, ó tán nù un. Kí páríkòkò máa tenu dùndùn wá ló kù, kí párigidi máa tenu bàtá jáde.

Rónké: Ti yín wá ń kó?

Babaláwo: Òké márùn-ún lowó òya tèmi

Rónké: A dúpé baba. N ó se gbogbo rè.(Ó fún baba lówó, ó fé máa lo)

Babaláwo: O se é o, pèlé o, kílé o, ó dìgbà díè

Rónké: E se é baba, ò o, a dúpé o . (Bí Rónké ti ń lo ni baba ń palè mó, tí iná sì kú)

[edit] ÌRAN KEFÀ

(AGÓ OLÓPÀÁ)

(Ní àgó olópàá, wón ti mú Olówu jáde, dídè ni ó wà towó tesè, ìhòòhò ni ó sì wà pèlú àfi sòkòtò nìkan tí ó wà ní ìdí rè. Wón ti fi nínà ba tirè jé. Se ni tojú timú rè ń se èjè wòrù tí gbogbo ara rè sì wú kúdukùdu bí eni tí àrùn òkè-ilè n bá jà)

Tàfá: (O ń wó Olówu nílè tuurutu) Bó síbí sá. Tó o bá yo nínú èyí, ìwo fúnrà re lo ó so pé o ò se béè mó. Ó ti léwájù atiro, o ti kéyin atiro, o sì ti rí nnkan tí kì í jé kádìye tò. Omodé re gbóhùn orò, ó sá sínú igbó, kò mò pé ibè gan-an lorò ń gbà bò. O wá sá fáwa olópàá, o sá sí ibi ibo Mògún. O rò pé àwa è é débè ni ? Mògún, Mògún gbogbo wa.

Olówu: (Ó fi owó nu èjè ètè rè nù) Kí ló tile dé? E è dè rora se mí. Mo jalè ni àbí mo pààyàn? Kí le tile pé mo se pàápàá?

Àjílé: O ò tí ì mohun tó o se? Àh áh àh, ó féè yé o ná. Ilé èlùlùú lo towó bò, o si ti fowó gún. Ìyà tí yóò je ó yóò ju tolè lo, apànìyàn pàápàá ń yájú ni. Àkò re tó se tán tó ń bá òbe díje, kò mò pé inú ni òun yóò ti gba ogbé wá. Àsé o kò tilè lè se jù báyìí lo. Sé wón ní ti a bá ń gbúròó olóburò lókèèrè, a ó ní bí kò térin yóò pò jefòn lo. Ijó tá a bá fojú kan olóburò la ó mò pé kò tádìye. Mo rò pé o ó lè pa itú méje tódé ń pà ni? Ibi tí Olórun ti se tán tí yóò mú ìgalà re, ó gbópàá, ó wá músée peranperan yá. O wá sá lo ibi ìbo Mògún. N kò tile mò pé se ni sàkì re ń se bí òrá. O sì wá ń sun àsùnjorunpá bí ení jeun yó. O wá kan àkànpo èwù bí eni ará rò. Ó sì ń fò, ó ń to ní ojó òhún ní ìbi ìbo Mògún bí eni pé kò daràn sórùn. Njé tá a bá fi òtún we òsì, tá a fi òsì we òtún kó ni owó yóò fi mó? Bíjoba ti ń gbé e kíwo náà máa bá won fowó tì í kó lè dára. Iró, òrò tìre kì í se béè, oyè bàsèjé lo je; Oláńrèyìn sì loóko re. Sé bóòsà kò sì lè gbèèyàn, a sì feni náà sílè bó se bá a. Kéku má je sèsé, kó má sì fi se àwàdànù. Tìre kì í se béè. Bí isin ti ń sode kódò kún, béè ni koro tire ń se kó fà …

Olówu: Kí e si ì mò pé adìye ìrànà ni ò, kì í se eran àjegbé. Gbogbo ayé ni yóò béèrè lówó yín nnkan tí e bá ní mo se. Olórun ni kò kúkú fún adìye yín lókó, è bá fojú ààtàn rí nnkan. Tàfá: Àìlókó adìye ń kó? Eékánná rè lásán tó. O sèsè bèrè. A ó fojú re rí mòbo. Olórun yóò máàfáà ni, kì í sojú omo kéú. Bí ó tile jé pé ìkà la se, kílè tó pòsìkà ń kó? Ohun gán-ná-gán-ná yóò ti bàjé. A ó fi yé o pé eyín mú ju òbe lo. Wón ní eye tí ó bá bèrù òkò ní í pójó, ń se ni eye tìre dúró de òkò tí ó ń kà á, ó sì ti bá òkò wálè.

Olówu: Òrò kúkú féré dójú ògbagada ná kí e tó mò pé òràn tí e kò ní í bó nínú rè…

Àjílé: Ta ló dáràn? Àbí o kò meni tó ò ń sòrò sí ni? Eyí tó ò bá fi máa bè wá bóyá a lè síjú àánú wò é. Omo òyà re wá ń pe ara rè lódù. Sùgbón kó tó dodù náà, ojú rè yóò rí tó (ó gbá a ní kóńdó lórí). Èrò tììì léyin olè, àgbon gbáà lórí eni sè, àdá aládàá, wàì lára igi. (Òyì ako gbé Olówu sùgbón kò pé tí ojú rè fi wálè)

Olówu: Bí owó kò se í sán bí a ká a lérí ni kò ní láìfí. Bí opé bá di opélopé àlè ìyàwó eni, bí a kúkú rójú kú kí a gba òrun lo ni kò ní èèwò. N kò lè torí i námò pe màlúù ní bùròdá kí n torí iyán je eran tí lùkúlùkú gbé, èmi kó. Nnkan té e bá fé kí e fi mí se, tenu mi kò ní í kúrò ní enu mi bí e ó pa mí. Eyin té e tún jé dúdú tó ye ké e máa ran dúdú egbé yín lówó láti ja ìjàgbara, iró, e kò se èyí, eni a pè wáá wo gòbì ló tún so pé gòbí senu góbigòbi ti e so ara yín di ajá òyìnbó kalè. Béè, bí mótò kò tí kò rìn, ajá lásán a máa gbòn ón lo. Gbogbo ìlú ayé ló ń gbégbá orókè sùgbón èyin ń kó? Bé e tilè fé se é, ònà dà? N se lògiri inú ilé gbàbòdè lówó tòde, tóòrùn se tán wá ń pa ni nínú ilé. Ebi ló ń pa ni tólóse ń polówó, ìgbà tá à wenú, a ó se wèdé? Bá ò gba òmìnira, a ò lè ní ìdàgbàsókè olóódoó nítorí àwon tó ń se ìjoba wa yìí, ìfé afadìye ni wón ní sí wa. N kò sì bá won wí sá. Kò sí eni tí yóò ro èkuru tí yóò fi owó rè ralè, ń se ni yóò pón on lá. Àbí ìgbà tí o rí Gbàdà tí o kò gba towó rè, tó o rí Múdá tí o kò mú un nídà, ti o rí eni ti eégún ń lé tí o kò gbé e ní okà, o sì ní o ó jeun àwon ará òrun, n kò mojó tó dà. Sé bí bí a tilè rán ni ní isé erú, à sì fi tomo jé e. Mo ní kí e jé kí n se onídùúró fún ara mi gégé bí ààyè mi kí ń fi lè rí agbejórò mi, e kò gbà, e fàáké kóri, e ta won-nle bí aja òyìnbó, ó dàbí ajá won tilè ni yín, folo fóló, ogbéni So-n-bí gbogbo (Won kò jé kí ó sòrò mó tí won fi bò ó bí ità bo eyìn tí wón ń lù ú bí ení lu bàra)

Tàfá àti Àjílé:- Ta ni ajá? Ta ni So-n-bí? Ta ni folo fóló? Orí re ni ajá. Orùn re ni ajá. Gbogbo ara ilé yín ni folo fóló. Gbogbo ìran yín ni So-n-bí. (Wón se bí eré, wón lu Olówu pa. Kò pé náà tí enì kan kan ilèkùn tí ó fé wolé, wón yára pa òkú Olówu mó nílé)

Músá: E pèlé o. Òrò Olówu ni mo bá wá bí o.

Àjílé: Olówu wo?

Músá: Olówu tí e mú ní ibi ìbo Mògún

Tàfá: Sé okùnrin tí ó wòlú ní ònà tí ó lòdi sófin tí ó sì bèrè sí ní í pín ìwé tí ó lè da ojú ìjoba Ògùdù bole fún àwon ènìyàn?

Músá: Èmi kò mo nnkan tí ó se. Mo sá mò pé e mú un ní ibi ìbo Mògún, Mo sì fé se onígbòwó rè kí e lè dá a sílè títí òrò rè yóò fi dé ilé ejó.

Àjílé: Ó mà se fún o ò. O ló ò mo ohun tó se? Odidi agbejórò? Mo se bí enì kan ló so fún o pé wón mú un? Eni tí ó so fún o ibi a ti pa ekùn kò sì so ibi tí a ti tà á fún o? Àwon moríyíná re kò sì so nnkan tó se nígbà tí won ti mo ibi tí a ti mú un? Kò burú, kó lè dára náà ni. Kò sí Olówu ní òdò àwa níyìn-ín o.

Músá: Níbo ló wa wà? Àbí ibí ko ni àgó olópàá òkè ojà tí mo mò bí ení mo owó?

Àjílé: Láti ìgbà tó ti débi tó kò tí kò jéun, tí a sì rí i wí pé ó fé di àìsàn sí i lára ni a ti gbé e lo sí ilé ìwòsàn, kí a má wá di eni tí ó ń ní òkú lórùn. Ko-lórùn- òràn ló bí ìyá ìyá mi.

Músá: Ilé ìwòsàn kè? Láti ìgbà wo?

Àjìlé: A ti ń wo ojú rè láti bíi wákàti mélòó kan bò. Kí ó má se di nnkan tí yóò yíwó la se gbé e lo láìpé yí

Músá: Ìwé owó té e gbà ti ibè bò dà?

Tàfá: Òrò olópàá kò ní wí pé a ń gba ìwé owó

Músá: Báwo ni a se lè rí í báyìí? Wóòdù ibo ló wà?

Tàfá: Won kò gba enikéni láàyè láti rí i

Músá: Ó fi kanra èmi agbejórò rè?

Tàfá: Bèé ni

Àjílé: Ta ló gbà ó ní agbejórò fún un gan-an?

Músá: Kò sí nnkan tó kàn ó nípa ìyen. “Báwo ni mo se lè rí i?”, ni mo bèèrè

Àjílé: Kò burú, máa bá tábilì sòrò nígbà yen.

Músá: Iwo yóò tún nnkan tó o so yen so ní kóòtù o. O kúkú mò pé òro ti wá kúrò ní eja-n-bákàn? Bó sogún odún, akàn ni yóò se. Iwo jé kí ìyàálé na omo ìyàwó rè wò, kíná wá ràn, kó wa ku omo eni tí yóò kiwó bò ó. Àwa sá lomo eni tí ń rojó bí kì í tilè se àwa lomo eni tí yóò dá a. Síbè, kánkán ni tewé iná, wàràwàrà là á toko èsìsì í bò, afowó-múná è é dúró wíjó. Ní tiwa bífá fore, àgunlá ifá, bópèlè fore, àgúntètè òpèlè, kórò Olówu sá ti fòre kábùse bùse. Sùgbón o, ké e má gbàgbé o, pójú yóò túnra rí ní kóòtù o.

Àjílé: Ó pé. Bóyá Olórun Oba ló wà ní kóòtù yín yen ni. Ìwé ìpèjó ni mò ń retí. (Ó wo Tàfá) À bó ò rí gúdúgúdú tó so pé igi yóò dá léyin ìyá ìlù.

Músá: N se ni kò yé o pé kíkéré tí gúdúgúdú kéré kì í se egbé dùndún, àbí ìwó rí ibi tí adìye ti mi abéré rí? Ó sèèwò. Mo sáà gbódò rí i wí pé o jìyà sí nnkan tí o so yen ní. N ó lo sí ilé ìwòsàn, n ó sì lo wo ìwé tí wón fi gba àwon aláìsàn wolé ni òní yìí kí n lè fi rí Olówu, kí n wo àlàáfíà re kí n sì mo ohun tí n ó so fún ìyàwó rè. Sùgbón kí èyin méjèèjì má gbàgbé pé ojú yóò tún ara rí o. (Ó jáde)

Tàfá: Yeesà, agbejórò Olórun Oba. Àwon ańgéélì ni kí o fi wá mú wa níbi, kí o ti Gebúréèlì síwájú pèlú idà olójú márùndínláádóje. (Ó kojú sí èkèji rè). À bó ò ri oníyèyé, àlè àmùdá.

Àjílé: Tirè tilè kúrò ní yèyé, yéérí gidi ni. Ó rò pé àdáse wa ni kiní yìí. Kò mò pé láti òdò ògá pátápátá ni òrò ti sè àti pé kò sí ohun tí ó lè ti èyin re wá. Òro ti pé màlúù kú wàhálà bá òbe kì í se òro tiwa, àwa ò ní í te kóòtù dèyìn. Orùn elésè méjì ni elésè kan ń dáràn sí, wàhálà ti àwon ògá ni ìyókù.

Tàfá: Se bí wón ti so pé bí Olówu kú, hèn en en, bó kò tí kò kù, hùn un ùn. Se bí àwon àgbà ni wón máa ń so pé adìye a máa fò je nnkan tí a gbé lé orí ilé, ìwo ò mo ohun tí a ń se sí irú adìye béè ni?

Àjílé: Mo mò ón mònà. Se ni à ń gé e ní ìyé, ká gé e ní ìyé kí ó di òpìpì.

Tàfá: Hen en òo. Kí won wá lo pe Olówu òhún wá lónà òrun kó wá jàjàgbara fún won. Àwón olòsì. Ojú kúkú ti se tán ó ti ti babaláwo won báyìí, omo rè kú lósàn-án. A ó máa wò ó bóyá ewé ni yóò so pé òun kò rí ojú já ni tàbi àgbo ni yóò so pé òun kò lè wè. Olówu òhùn ló wá lo báyìí, a ó máa wo ohun tí yóò ti èyin rè wá. Won a sì máa dánnu, won a máa lénu bebe; “tó ba kú, tó bá kú”, àwon olùyà. O ò jé kí ń lo fàbò ohun tó selè tó ògá létí ná kí won tètè wá onísègùn ìjoba tí yóò yè é wò kí òkú ìgbé rè má dá òórùn pa wá níbí.

Àjílé: O ò puró o jàre. Èmi ò kuku rí oore kankan tó ń se fémi nígbà ó wà láyé. Àjàgbara; òmìnira, òmìnira la fé je ni? Ìyen ò se ànfàání kankan fémi rárá. Wón sá ní eni tó kíni tá à yó, aikíni rè pàápàá kò lè pani lébi. Eni tó wà láyé tí kò seni lóore, bó kú pàápàá, kò lè pani nípò dà. Ojú tàgádágodo won.

Tàfá: Ìwo lo tilè tún mú mi rántí òrò olómìniradé yen. Ojó wo ni àwon dúdú tó lè dá se ìjoba ara won gan-an? Wo gbogbo dúdú tó gbòmìnira, o ò rí i bí won se ń se ara won? Sé irú rè ni wón fé kó bá wa lÓgùdù mojò? Òmíràn á joba kárinkánse. Òmíràn á pa ará ìlú. Òmíràn á pa alátakò. Ibò tó gbé won wolé kò lè gbè won jáde mó. Kò sí ohun dúdú kò fi ojú dúdú rí tán. Owó ara won ni wón fi ń se ara won.

Àjílè: Òmìnira kó lèmi tilè ń pe èyí tí wón gbà yen, omi–ìnira lèmí mò ón sí nítorí wón ń gbà á tán ogba ni gbogbo nnkan ń le. Ojà á wón bí ojú, olóde ìlú á lé oba kúro lórí oyè, wón a kó owo ilè won lo sí ìlú òkèèrè. Àbò ò gbó, abé òyìnbó wù mí ju abé dúdú lo, ká má puró. Mo sì mò pé kè é sèmi nìkan, enu àwon òwó òmòwé wóńwé nìkan ló ń jàjàgbara, tálákà tébi ń pa kò mo ohun tó ń jé béè, ebi ò sá ni í wonú kórò mìíràn wò ó. Tá a bá sì lo sí òdò àwon tó ti gba omi-ìnira yìí tá a bèèrè lówó àwon ènìyàn ibè pé òyìnbó tó lo ni wón ń fé ni tàbí ìjoba tiwa-n-tiwa? Eye kò sokà ni won yóò fi ohùn kan so pé kí funfun ó padà ní wàrànsesà. Kán-ún yàtò sèèpè. Ó bó lówó omo tó ń jelè ká má so tomo tó ń jeérú. Dúdú kò dára, dúdú kò wùùyàn.

Tàfá: Òdodo ni gbogbo ohun tí o ń so, kò síró olóódoó ńbè páà. O ò jé n tètè lo sódò ògá òhún kí òkú eran isò ìgbàdo yìí tó di gíífà.

Àjílé: Kò burú. Èmi náà óò wolé lo rèé máa ko ohun tójú wa rí kale lórúko re. (Àwon méjèèjì kúrò lórí ìtàgé. Iná kú).

[edit] ÌRAN KÉÈJE

(INÙ ILE KAN LÓGÙDÙ)

Tólá, Ìyá Onídodo:- (Nínú ilè ìdáná, ó ń féná) He è é, a ò tilè mo ohun tí ó se igi yìí.

       Àbí òjó ti pa á ti ilé onígi wá ni? 

Bósè, Ìyá Oníresì:- (Ó wolé pèlú àwon nnkan tí ó sèsè rà tojà bò) Áh a á, mo

                               se bí enì kan wà lódò yín ni. E sì ń dá sòrò. Sé kò sí? 

Onídòdò: Kò sí. Igi yìí ló kò tí kò jo. Mo fé e, fé e, fé e, lóríi kò náà ni, túú ló ń rú. N kò mo ohun tó se é, bóyá òjó ti pa á láti ilé eni tí ó ń tà á ni, n kò mò. Mo sì ní n dáná díè ni o. Ohun tí yóò dáni dúró de onígbèsè eni, kí Olúwa má fi sí sàkáaní wa. Igi òsìsìrèrè yìí kò so pé òun kò fi òsì lo ènìyàn.

Oníresì: Hè è, Olòsì mà làwon onígi yen. Wón lè figi mímí se gbígbe féèyàn, kówó sá ti dówó ni wón mò. Wón á tilè máa sako. Wón a ní bálángbá se jé sára ògiri, tí gòlúgò se jé sógòdò, béè gélé ni igí jè sì àwon. Hùn ún un, ayé bàjé, olorì ń nájà oko, onígi náà ń sako. Àwon náà ò ní í pé máa sé Múrí.

Onídòdò: Èyí ti mo mà rí nìyen o. Ká fi igi náírà kan se dòdò sísì. Olòrun ló mo ibi tí a ó bá ara wa dé ní ìlú Ògùdù yìí sá.

Oníresì: Mo mà kàn ń so tigi mà ni, igi nìkan mà kó. Àbí e kò rí gbogbo jíje mímu bó se dà lójà ni? Gaàrí wón, ó jojú lo. Ata ò seé kàn. Ma débè lepó dà ní tire. Ayé àtijó ni wón ti ń so pé eni tó bá ní sílèkan yóò ní abó, yóò níyàwó tó bá délé olókà. Láyé òde òní, náírà márùn-ún kò délé olókà bò. Ìtàkùn tó sì so agbè náà ló so légédé, gbogbo èyí náà kò sì sèyìn-in funfun.

Onídòdò: N kò tilè mo ibi tá a máa bá yààrá já nílè wa yìí. Gbobgo àwon ìlú tí kò fi ara mó ìjoba amèyà ni wón kò tí won kò kó nnkan wá sílè wa mó. Àfàkàn àfàkàn sì ni òrò yìí. O ò rí i wí pé a kò rí epo wa okò mó tí òrò fi di kélésè mésè le. Àìrí epo yìí sì ń dààmú àwa olóńje torí ń se ló ń jé kí owó ojà lo sókè. N kò si rò wí pé a lè fi ìgbà kan rí epo wà ní ilè yí láé tí bèlà yóò fi fun fèrè àfi tí iyán yóò bá se tán tí yóò di jíje gànbàrí ní Sókótó. Àlá tí kò lè se nìyen, àláa Kurumó.

Oníresì: Èwo tún ni àláa Kurumó?

Onídòdò: Àwon ènìyàn dúdú kan ni ó ń jé Kurumó. Tí òyìnbó bá ti òkè òkun dé, àwon ni ó máa ń ru òyìnbó gùnkè. Ó wá se, òkan nínú won wá ní òun lá àlá, òyìnbó ru òun lé orí. O ò rí i pé àlá tí kò lè se nìyen kí ibi tí a pè ní orí wá di ibi ilèélè?

Oníresì: Àlá tí kò lè se ni lóòótó. Njé o tilè gbó ohun tí àwon kan ń so kiri pé àwon Òyìnbó yìí ti ń dewó? Wón ní àwon máa gbé omo wa sórí oyè.

Onídòdò: Iró mà ni. Kàkà kí ewé àgbon dè, pípele ló mà tún ń pele sí i o. Ta ni kò mo ogbón ká feran sénu ká wá a tì. Iró ni wón ń pón ní bébà tó ò bá mò. Béè, bá a pa téru láró, aso téru ni, bí a kùn ún lósùn, aso téru ni. Bí a tilè dì í ládìre pàápàá, ojú aláìmòkan ló ti lè yàtò.

Oníresì: Bèé, ìgbà kan lowó sì rí kíti kìti, nílè yìí náà ni, tí gbogbo ènìyàn ń fé aya méjì méta ní ròngbà, lójú wa náà ni. Sùgbón nísisìyí ń kó? Náírà ti di nára nàra, omó ti domokómo, ayá sì ti ń ya lo. Síbí ilé wá se tán, ó gbaludé. Onígaàrí fàbínú yo. Onípanla wá pèyìndá, èèyàn ò sòrè oníyán mó, a ò répo sèròjú obè mó. Nnkan lé, nnkan ò wò tó dífá fómo tó wá ra ráìsì lówó mi lóòórò àná. Ìgbà tí mo ti ní “Òfé nìresì, eran lowó, lomó bá je àsán ìresì, ló gbòndí gbúù. Mo lówó ń kó. Ó lóun ò jeran, ìresì òfé lòún je. Béè àìsí owó ló fá gbogbo sábàbí. Owó ò sí, èèyàn ò sunwòn, Kò sóògùn tó jowó lo. Àh à à, òrò n bá rò n tó ròfó. Mo mà gbó pé wón ti lu Olówu pa.

Onídòdò: Yéè yéè yéè, mo gbé o, n ò gbó.

Oníresì: Àní wón ti lu Olówu pa

Onídòdò: Sàn-àn-gbá ti fó. Ògunná kan soso tó kù fún wa ló tún bó sómi un, nnkan ti se. Ibo la wá fé bá yàrá já báyìí?

Oníresì: Kò ye mi o. Gbígbó tí a gbó, ń se ni gbogbo ojà dàrú nítorí wón ní kò kú fúnra rè, ń se ni wón lù ù pa.

Onídòdò: Àwon wo ló lù ú pa?

Oníresì: Àwon wo ni ìbá tún se bí kò se àwon ará ilé wa. Òrò hùn, hùn hùn a máa já nílé elédè?

Onídòdò: Sáwon olópàá? Àwon olópàá dúdú?

Oníresì: Àwon náà mà ni o

Onídòdò: Báwo ni síse báyìí? Nígbà wo ni kí á lo kí ìyàwó rè?

Oníresì: Kíkí kè? Bóyá won yóò ti lo sí kóòtù báyìí gan-an nítorí Músá tí ó jé agbejórò Olówu kò gba gbèré. Ó ti pé àwon olópàá léjó ní eye-kò-sokà. Wón ló so pé òun yóò rí i pé òun fi ojú àwon olópàá yen gbolè.

Onídòdò: Àwa náà lè lo sí kóòtù lo wòran nìyen. Kí á wòran tán kí á fi àbò sílé Olówu láti bá aya olóògbé kédùn.

Oníresì: Kò burú. O ò wá jé á múra sísé. Jé n lo gbé ata wá nílé (Ó jáde).

Onídòdò: Èmi náà ó lo kó ògèdè mi tó kù sítòsí (Òun náà fi orí ìtàgé sílè, iná sì kú).

[edit] ÌRAN KÉÈJO

(NÍ KÓÒTÙ)

(Gbogbo àwon ènìyàn pé jo, wón jókòó. Àwon mòlébí òkú jókòó sí apá kan. Àwon agbejórò gbogbo náà jókòó sí àyè won. Àwon olópàá náà wà ní àyè tiwon. Àwon onísègùn náà kò sàìwà ní ibè. Ò se, adájó dé, wón pe “kootu”, gbogbo ènìyàn dìdè, adájó jókòó tán kí gbogbo won tó jókòó)

Olá: Kí á tó bèrè ejó tí a ní lónìí tí ó wà láàárín olóògbé Olówu àti àwon olópàá, mo fé fi tó gbogbo ènìyàn létí wí pé kò sí àyè fún enikéni láti ya fótò nnkankínkan tó bá selè ní ilé ejó yìí. Nísisìyí, n ó késí àwon agbejórò láti so bí wón ti jé àti eni tí ò gbà wón ní agbejórò.

Òjó: Kémìí olá ó gùn. Pèlú àse láti enu agbejórò ìjoba àgbà àti gégé bí òfin se fi lélè, mo wá láti gba gbogbo nnkan tó bá selè ní ilé ejó yìí sílè láìjé kí òkankan jé atadànù bíi kiní ajá. Emi ni Òjó, igbákejì agbejórò ìjoba.

Olá: Káre o, o se é púpò, Ògbéni Òjó. Yóò seé se.

Adé: Kára ó le baba. Èmi ni agbenuso fún gbogbo àwon olópàá ilè yìí tí ó jé wí pé ní ònà kan tàbí òmíràn, wón so pé wón ní nnkan se pèlú ikú Olówu, ní pàtàkì, kí ó tó se aláìsí. Òdò agbejórò ìjoba àgbà sì ni mo ti wá.

Olá: O se é, Ògbéni Adé. Sé agbejórò tán àbí ó kù?

Músá: Olúwa mi, èmi ni agbejórò fún gbogbo ebí olóògbé àti ìyàwó rè ni o àti omo rè ni o. Àní èyí tí n ó fi pè é ní eéwèèwá méjì, n ó kúkú pè é ní okòó. Èmi ni agbejórò fún gbogbo ìdílé Olówu pátápátá. Ìyàwó olóògbé ni ó sì gbà mí ní agbejórò.

Olá: O se é púpò, Ògbéni Músá. Kí a má dá èènà penu, kí a má bá òpó lo sí ilé olórò, kí a má se béè gba ara wa ní àsìkò púpò, kí Ògbéni Òjó kúkú bèrè isé.

Òjó: E se é, olúwa mi. N ó kókó ka nnkan tí òkan nínú àwon olópàá wa, Ògbéni Tàfá, ko sí ilè tí ó lo báyìí: “Èmi jé òkan nínú àwon olópàá ní ìlú Ògùdú yìí. Ní ojó kan ni wón fi tó mi létí wí pé enì kan ń pín àwon ìwé kan káàkiri ìgboro tí ó lè mú kí àwon ará ìlú fa ìjàngbòn. Mo tún gbó wí pé okùnrin kan tí ó ń jé Olówú tí a ti lé kúrò ní ilè yìí ń padà bò láti ní owó nínú nnkan tí ó je mó ìwé tí mo so pé wón n pín yìí” “Gégé bí èyin náà se mò wí pé òpòlopò nnkan ni a fi àyè rè sílè ní ilè yí sùgbón kì í se ìwà burúkú, a kò gba òsi láàyè.” “Wón ní, àìdúró nijó, mo múra, mo lo sí èyin odi láti pàdé Olówu. Kò pé náà tí mo dé ibè tí mo rí mótò ayókélé funfun kan tí ó ń bò. Sé bí inú bá se rí ni obì ń yàn, Olówu ni ó wà nínú okò náà pèlú okùnrin kan báyìí. Nígbà tí mo dá won dúró, òrò ìsokúso, òrò kòbákùngbé ni wón bèrè síí so sí mi, ìyen àwon méjèèjì tó wà nínú okò náà. Wón wíjó lo kánrin sùgbón láìfòtá pè, mo ní kí won jáde. Wón kò, wón sì fi ogbón àlùkóróyí lo mó mi lówó. Ìdi ìbo Mògún ni owó èmi àti àwon elegbé mi ti wá te wón.”

“Nígbà tí a dé àgó wa, mo bèèrè lówó Olówu wí pé se bí wón ni kó má dé ilè yìí mó ni wí pé ìwé àse tó fi wo ìlú dà? Ó ni òun kò ní ìwé àse kankan, nnkan tí mo bá fé kí n se, awo kan kò kojá ikú. Bí ó ti so eléyìí tán, ìpàkó ni ó ko sí mi tí ó bèrè síí rín èrín ìyàngì, ó ń fi mí se eléyà. Ibi tí ó ti ń se eléyìí ni ó ti subú lu sófà, ìyen ìjokòó tí ó wà ní ilè, ó sì dá a. Wón ní eni tí ó rán ni nísé ni à ń jé àbò fún. Mo fi tó ògá wa pátápátá létí wí pé Olówu wà ní òdò mi. Ó ní kí n fi í sí àhámó ni òdò mí di ojó kejì kí n tó mú un wá sí òdò òun”. “Bí gbogbo rè se mo nì yí, olúwa mi.” (Òjó lo jókòó. Músá jáde, ó sì kojú sí Dàání, òkan nínú àwon olópàá).

Músá: Wón ti fi ìwé kan sowó sí wa láti òdò adájó kan tí ó rí Olówu ní òdo yín. Adájó yìí ní òun bèèrè lówó Olówu bóyá ó ní nnkan láti so, ó ní nnkan tí ó so nì yí “Mo bèèrè fún àwon nnkan tí ènìyàn lè fi wè gégé bí ose, omi àti kànhìnkànhìn, won kò fún mi. Mo ní kí won fún mi láàyè láti máa ra ońje tó bá wù mí, èbà nìkan ni mo ti ń je láti ìgbà ti mo ti dé ibí. Njé ìhòòhò ni ó tilè ye kí n wà láti ìgbà ti mo ti wà ní àtimólé?” Kí ni ó dé tí e kò fún Olówu ní aso?

Dàání: Àse tí wón fún wa ni a ń pa mó

Músá: Látì ibo?

Dàání : Látòdò ògá pátápátá.

Músá: Njé òfin ilè yìí gbà yín láàyè láti so eléwòn sí òkolonbo?

Dàání : Àse tí wón fún wa ni a tèlé. Wón ní ó lè fi èwù yìí pokùn so.

Músá: Wón ní e kò jé kí ó jáde náà?

Dàání: Béè ni

Músá: Wón ní tí a bá ké igi ní igbó kí á fi òrò ro ara eni wò. Njé kò tilè ye kí e gba eni tí e pè ní arúfin yìí láàyè láti gba atégun sí ara bí?

Dàání : Àse tí wón fún wa ni a ń tèlé

Músá: Ó dára kò burú. Njé e tilè lè so fún wa eni tí ó fún yín ní àse yìí pàápàá?

Dàání : Àwon ògá pátápátá

Músá: Ní ibo?

Dàání: Ògùdù yìí náà ni

Músá: Iyen Àbú?

Dàání : Béè ni (Dàání lo jókòó, Músá kojú sí Àbú)

Músá: Ògá pátápátá, wón ní e ní kí Olówu má wo aso kankan?

Àbú: Béè ni

Músá: Dàání ti so ìdí tí e fi so èyí sùgbón lékè eléyìí náà, e tùn fún un ní aso ìbora. Sé olóògbé náà kò lè ya eléyìí téérété kí ó fi pokùn so?

Àbú: Irú rè kò selè rí. Ń se ni wón máa ń gbìdánwó láti sá àsálà, won kì í fi pokùn so.

Músá: A tún gbó pé dídè towó tesè ni eléwòn náà wà títí tó fi kú.

Àbú: Kò sí iró ńbè.

Músá: Lóòótó, a mò pé ajá jìnà sí ènìyàn bí kókósè se jìnà sí orí. Nje tí ìwo bá ní ajá kan, o lè dè é mólè fún ìgba pípé láìtú u sílè nígba kankan?

Àbú: Tí ajá bá ti ya dìgbòlugi tó lè se ènìyàn ní ìjànbá, mo lè dè é fún odún. Nípa òrò Olówu, bí nnkan se rí gélé nì yí.

Músá: Ìyen ni pé ogba ni ajá dìgbòlugi àti Olówu nínú isé ibi sí ènìyàn?

Àbú: Mo se gbogbo ohun tí mo se láti dáàbò bò ó ni.

Músá: Kì í se nnkan tí mo bèèrè lo dáhùn, síbè náà, a rí òótó tí kò fara sin nínú ìdáhùn re. Ààbò ológbò sí èkúté, ti ekùn sí eran ìje. O sí rí i pé ó yorí sí rere náà, àfi ìgbà tí o rí i wí pé ó kú?

Àbú: Gbogbo agbára tí mo ní ni mo sà láti fi rí i wí pé ó wà láàyè. N kò fé kí ó kú. Àmúwá Olórun ni.

Músá: Ó sì ye kí o mò pé Olórun è é sebi, àwa èdá owó rè la ò sunwòn. Kí a tilè pa ìyen tì. Irú ètó wo ni o ní láti de ènìyàn eléran ara bíi tìre mólè?

Àbú: Gégé bí ògá pátápátá, mo ní agbára láti se é. Ofin gbà mí láàyè láti rí i wí pé kò sá lo. (Músá lo jókòó. Adé tí ó jé agbejórò fun àwon olópàá dìde)

Adé: Àbú, a rí i gbó wí pé bí ó se wu àwon ènìyàn yín ni wón máa ń fi ìyá je àwon eléwòn tí wón bá kó sí abé ìtójú won, ìlò yààà bí omi òjò, àlòyó bíi tóró àtijó, àlùdè bíi mààlúù tó kángun sí Fúlàní. Sé òótó ni?

Àbú: Rára o. A kì í fi ìyà je àwon òdaràn. Sùgbón òpò ìgbá ni àwon òdaràn máa ń yowókówó. Tí wón bá se èyí, a máa ń so fún won pé kí wón ti owó omo won boso.

Adé: Njé a tíì rí enì kankan kí ó pe àwon ènìyàn re léjó sí kóòtù wí pé e fi ìyà je òun rí?

Àbú: Kò sí eni tí ó pè wá léjó béé rí. Sùgbón ó dàbí ìgbà pé àwon oníwèé ìròyin àti àwon òmòwé kò fi béè féràn wa.

Adé: Emi náà mò wí pé òpòlopò àríìríso ni ó ń káàkiri ìgboro nípa yín. Mo kàn bèèrè àwon ni kí á fi lè mo ìdí òkodoro ní íle ejó yìí. (Awon méjèejì lo jókòó, Músà dìdè, ó kojú sí Súlè)

Músá: Àwon ènìyàn re so pé e kò fi ìyà je Olówu. Sùgbón ní àkókó, ó kò láti sòrò, nígbà tí ò se, ó tún gbà láti sòrò. Kí ni o rò pé ó fa ìyípadà okàn yìí?

Súlè: Mo tóka sí òfin ilè wa kan tí ó kàn án nípá fún un láti sòrò ni ó jé kí ó so ó.

Músá: Njé o mo nnkan tí ó selè sí Olówu ní ìgbà kan rí saájú ìgbà tí e mú un yìí?

Súlè: Wón fi i pamò sí inú túbú

Músá: Ojó mélòó ni ó gbé ní ibé?

Súlè: N kò mo iye ojó tí ó gbé

Músá: Jé kí n rán o léti. Ojó mókànlélógórùn-ún ni.

Súlè: Hèn èn én? Kí ni a ti fé se ìyen nínú òrò tí ó wà nílè yìí?

Músá: O sé é. Nnkan tí mo kàn fé fi yé o ni pé títí gbogbo ojó yìí, ojó mókànlélógórùn-ún, kò gbin, kò fohùn. Ìwo wá fi òfin kan hàn án ní òtè yìí, ó ti yára ń kako. Odoodún àti bí ojó se ń yí lura ni ènìyàn máa ń gbón sí i sá. N kò ní í jé kí á fi èyí gba ilé ejó ní àsìkò jura lo. Mo kàn fé láti tóka òdodo tí ó wá nínú òrò yìí hàn ilé ejó ni. Ti a bá sá so pé mò ón, òmòràn ní í mò ón. Jé kí á gbàgbé ìyen ná kí á tún bi elòmíràn lórò. (Súlè jókòó Sálísù dìde). Ògbéni Sálísù, gégé bí àwon onísègùn ti fi tó wa létí, wón ní ó dàbí ìgba pé e rí Olówu.

Sálísù: Béè ni

Músá: Njé o tilè lè là wá lóyè bí Olówu se fi orí sèse?

Sálísù: Rárá o, torí ilè tí kò ti ojú eni sú, òòkùn rè sòro í rìn. (Sálísù lo jókòó, Súlé tún ìde)

Músá: Súlè, wón ní agbà eégún ní í mo òjè í kì, ìwo ni n ó bi ní ìbéèrè yìí. A rí i kà nínú akosílè re wí pé ní ojó tí ìsèlè a-forí-pa yìí selè, ń se ni Olówu dédé dìde bí eni tí nnkan ta lé tí ó fò sókè bi ológbò tí iná jó lésè tí ó sì gbé àga tí owó rè bà tí ó jù ú lu olópàá kan. Sé òótó ni?

Súlè: Béè ni

Músá: O ní léyìn èyí, ó tún lo bá olópàá tí ó wà ní itòsí,ó tún kó ìkúùkù bò ó?

Súlè: Béè ni

Músá: O ní òpòlopò olópàá ni ó kojú Olówu kí e tó lè ségun rè

Súlè: Àwa márùn-ún la kojú rè.

Músá: Ní ibi ti gbogbo yín tí ń yí ara yín sí ebè yí ara yín sí iporo, njé enikéni lu Olówu?

Súlè: A kò lù ú, nígbà tí kì í se eran. Òun ni ó fi orí sán ògiri fúnra rè.

Músá: Ìyen ni pé apá ní ń jé apá, itan ní ń jétan, gèngè àyà ń jé gèngè àyà, kò sí ibì kankan tí e ti fi kóndó gbá Olówu nínú won?

Súlè: Kò sí?

Músá: Kò burú, òrò kan Onísègùn Awósanmí.O se àyèwò sí opolo Olówu

Awósanmí: Béè ni

Músá: Eni tí ó tún ràn ó lówó láti se isé yìí ni Onísègùn Olú.

Awósanmí: Béè ni

Músá: Jé kí n ka díè lára ìwé tí Olú fi owó ara rè ko sílè nípa Olówu “Opolopò ibi ni opolo yìí ti bàjé tí ó sì jé wí pé kì í se ojú lásán”. Sé òótó ni opolo náà bàjé? O kè?

Awósanmí: Òótó ni. Bí kò jé béè Olú kò ní í so béè.

Músá: Njé sísubú tí Olówu subú ni o rò pé ó fa gbogbo egbò yìí?

Awósanmí: Ó lè jé béè.

Músá: Tí a bá fi bíi kóndó nà án ń kó?

Awósanmí: Ìyen náà lè fà á.

Músá: Kò burú, enu nnkan tí mo fé gbó nìyen. E se é. Ó ku òrò kan tí mo fé bi Àbú. (Awósanmí lo jókòó, Àbú tún dìde) Mo rí i kà nínú àkosílè re kan tí o so pé olóògbé Olówu ń díbón wí pé ara òun kò dá.

Àbú: Ó sèsè wá tànmó-òn sí mi pé olóògbé náà kò díbòn ni.

Músá: O tán nínú mi (Awon méjèèjì lo jókòó. Òjó dìde, ó kojú sí Làtí)

Òjó: O kó isé ìsègùn dé ojú àmì ó sì ti pé tí o ti n se isé yìí?

Làtí: Òótó ni. Bí ojó Béélò se pé ní Ìlorin tí tàwùjè se pé látàrí béè ni tèmi náà se pé pèlú ìsègùn.

Òjó: Gbogbo ènìyàn ti mò pé isé lanúlanú àti pófunpófun ni o ń se?

Làtí: Yíye ìfun, èdò, àpólúkú àti gbogbo nnkan tí ó bá wà ní ara ènìyàn wò ni isé mi.

Òjó: Kò burú. Músá, ó dowó re. (Músá dìde)

Músá: (Ó kojú sí Làtí) Wón pè ó pé kí o wá ye Olówu wò àbí?

Làtí: Kò síró ńbè

Músá: O sì yè é wò?

Làtí: Mo yè é wò mònà. Isé mi sá ni

Músá: Nínú àkosílè re, o so wí pé o se àkíyèsí egbò kékeré kan ní abé ètè Olówu àti pé ètè náà wú bí ètè eni tí agbón ta?

Làtí: Béè ni

Músá: O tún ní o rí ibi tí ó dàbí ìgbà tí a fi yá ògiri ní apá rè?

Làtí : Mo rí i

Músá: O tún rí i pé apá àti esè rè wú?

Làtí: Tàpá tesè rè ló wú bòmùbòmù.

Músá: Njé o bèèrè ìbéèrè kankan lówó Olówu?

Làtí: Mo bèèrè

Músá: Njé o se ìwádìí bí ó se fi ètè gba ogbé bóyá ìgbátí ìgbámú bí i ti keríkerì ni?

Làtí: N kò se ìwádìí

Músá: Njé o se ìwádìí bí egbò apá rè se dé ibè bóyá patiye ló gbó mó on lára tàbí kóńdó ni wón kán mó on?

Làtí: N kò bèèrè

Músá: O sì ló o bèèrè òrò lówó Olówu. Kí lo wá bèèrè lówó rè gan-an nígbà tí ó jé pé àlàáfíà rè tí ó ye kí ó je ó lógún kò je ó lógún? (Ibi tí wón so òrò dé nì yí tí adájó fi pe Olá tí ó sì so òrò kélékélé sí i létí, ìyén sì wá dá gbogbo ènìyàn ní menu)

Olá: Ó tó. Ní ibí yìí ni a ó dá ejó dúró sí, a sì sún un síwájú di ojó mìíràn. (Wón pé “kootu”gbogbo ènìyàn dìde dùró, adájó jáde, àwon ènìyàn náà sì ń jáde ní méjì, méta. Iná kú).

[edit] ÌRAN KÉSÀN-ÁN

 (NÍLÉ OLÓWU)
(Léyìn ìgbà tí gbogbo  ènìyàn ti  kúrò ní ilé ìdájó tán, òpòlopò àwon 

ònwòran ni ó bá Rónké wálé. Aso dúdú ni Rónké wò. O se, wón délé, gbogbo won lo jókòó sí pálò)

Rónké: E se é o, e se é, a dúpé o, e ò ní í firú è gbà á o.

Bàbá Òkè Ilé: E sáà jókòó báùn. Gbogbo rè náà ni yóò ní ìyanjú. Won yóò fi ìyà tí ó tó ìyà je àwon olópàá yìí. Sé ó pé tí wón ti ń se. Ojú won yóò rí àtàláátà baba àlààrùba.

Ìyá Ojà Oba: KÓlúwa sáà bá wa wo àwon omo yìí

Yèyé Òkèrèwè:Bógèdè ò kú omo è é rópò rè. Àwon omo yìí náà ni yóò gba isé baba won kanri. Won yóò sì se é ju baba won lo. Àwon ni yóò tilè sì gbà wá lówó funfun nítorí wón ní kÓlórun jé kómo eni juni lo, àdúrà àtàtà.(Omo tí won dárúko yìí mú kí ekún gbon Rónké. Ó bú gberegede, gbogbo ènìyàn sì ń bè é)

Rónké: (Pèlú ohùn arò) Ikú ò jémi lóni mó, òrun lònìyàn mí wà. Eyin asekú pani, èyin asekú pààyàn, e ó jìyà látayé lo dálùján-ánnà lágbára Olúwa.

Akígbe àkókó: Mo ni kó o fi wón sílè máa wòye

O jé n pomo olá, omo ekùn

Olówu o, omo fún-n-ké ò

Ká tó rérin ó digbó

Ká tó réfòn ó dòdàn

Ká tó réni tí ó se bí Olówu

Ó dòrun.

Òkansoso ìbènbé tó kojá egbèrún ìlú

Omo Oláníkèé, omo Aráyeni, omo Èyíwùmí.

Kólédafé ò, Arígbábuwó ò

Akékarakára kólòrò ó gbó omo gbómo fágàn

Òsùpá se bí eré wòlú

Aréweyò, Dáradóhùn, omo Olówulógùdù tí ò sí láyé mó

Òrun dákun delè féni ó lo

Kó o sì dákun má kánjú mó, gbogbo wa là ń bò

N ó pè ó bí ológún erú

N ó pè ó bí ológbòn níwòfà

Omo Tèmídayò tó se bí eré pàwò dà

Dúdú ò ní í gbàgbé re

Gbogbo ajàjàgbara ni ó máa rántí re sí rere

O lo sórun lòó simi òrun rere

Òrun ènìyàn àtàtà

Kò séni tí ò níí ròrun

Kò séni tóko baba rè ò ní í dìgbòrò

Wón ní bó ti wù tá a perí àkàlàmàgbò tó.

Ó gbódo légbèrún odún láyé dandan

Sùgbón ó se ó pò, àkàlàmàgbò èyì ti podún je láìwèyìn.

Òwò àdá mò ti kádá léyín, igi dá

Olówu wáá kú tán, ewúré ilé ò réléèpo

Àwon àgùntàn, won ò rólógèdè

Òbòró ojú gbòdó oko omoge

Ìgbín tí ń ràjò tó filé rè kérù

Omo ojú pón koko kò fó

Igi ńlá tí ń sorógbó

Èyí règèjè tí ń sobì

À ń lé e nílùú ó tún ń molékúnlé

Òsíkí alángbá wèwù èjè

Afárá se bí eré, ó dá

Ká kán ludò ló kù

Eni afisé ògbàgbà rán tí ń gbani ti lo

Tapó wá se bí eré ó wonú apó

Ó gbénú apó

Tapò wonú àpò ó wolè síbè

Mo ní àti tapó àti tapò

Tó bá wonú agbòn, a dìpà ode

Àti mímò-ónse re, àtàìmò-ónse re, Olówu

Káwon èrò òrun máa bá o se é

Kórun dèdè dákun delè féni ó kú

Mo kúkú mò pé o ò so pé o ò jeun mó.

Àwon olòtè ló jékú yowó re láwo

Eyin tó o fi sílè kÉdùmàrè jé ó dàkùko


Rónké, mo ní o rójú, ojú là á ró

Torí òfò lo sará yòókù

Gbogbo wa la meni ohún se

Orin: Njé tá a bá dàgbàdàgbà

Tá a bá wonú ilè

Omo eni ní o wolé deni

Akégbe Kejì: Ó tó. Mo ní o jé n gbà á lénu re

O tó so ó dorin

Torí mo bokùnrin jé ńjó mo gbó nnkan àdélé wí

PÓlówú towó olòtè filè bora bí aso

Omo awo tó relé tó ròrun rè é simi.

Mo kégbe àké ìsimi lójó òhún

Mo ròkè rodò láìsosè wò

Gbogbo ayé pa lóló wón dáké lo kánrinkánse

Omodé kò, won ò jeun

Àwon pínnísín kò, won ò kígbe oyàn

Aráyé ń ké, ará òrun ń fohùn

Sàngó ń ké, béè lOyá ò dáké

Ìkòkò kò, won ò rodò

Apé kò, won ò sesu

Odé kú, ó lo sí Mòro

Àgbè gbékú mì tòun tebè rè

Ikú pa gbani-gbani, ó pÓlówu

Omo asogbó dilé

Asògbé dìgboro

Ó ní ká múrá, ká gbara wa

Njé ta ló lè jàjàgbara bí tOlówu Rónké.?

Oká ojú ònà tíí wú bamùbamù

Apani ká tó fowó kan sèkèté

Aponi lóòyì ranyin ká tó débi agadagídì.

Ó torí dúdú gbégbó

Ó torí dúdú gbégbèé

Ó titorí dúdú gbéjù láàárín oko

Eni ńlá, èèyàn iyì tá a fi í joba

Mo níwo loba láàrin òpò èèyàn

Torí gbajúmò lónìlú, ń se loba ń pàse

Iró lowó ń pa, omolúàbí ló jù

Agbé kú, òrò aró dópìn-ín


Àlùkò kú, a ò tún rósùn mò

Atòrun wá solùgbàlà bí i ti Jéésù bí i ti Mò-ón mò.

Njé a ò níí gbàgbé re o, omo Ògùdù mosù

Ò torí ìjàgbara, ó lésè gígùn

Ó torí dúdú, ó fira rè wólè

Àwa náà ò nì í sùn

A ó máa se é lo níbi tó o bá a dé.

(Gbogbo ewì tí wón ń ké àti àròfò tí wón ń fò, ekún ni Rónké ń sun àti àwon omo Olówu. Ìgbà tí àwon akéwì sì dáké tí wón rò ó tí kò gbó ni wón ti mú un pèlú àwon omo wolé lo, gbogbo ènìyàn sì tèlé won, iná sì kú).

[edit] ÌRAN KEWÀÁ

(NÍ KÓÒTÚ)

(Iná tàn, àwon ènìyàn ń wolé wón sì ń tàkúrò so kí adájó tó dé )

Bòdé: (Ó bo eni tí ó bá lórí ìjokòó lówó ) Ikéowó oko Mopélólá, gùùkàn èyìn orùn nínú pílésò. Ìwo náà wà?

Láyí: Agùntásoólò oko Adéolá, Àyìndé agbélékalèbíère, Ó torí elégàn, ó légbèrin òré, ìwo nù-un? Emi náà wá.

Bòdé: Sé o wá ní ìjósí náà?

Láyí: Mo wá mònà. Ta ni kò ní í wá sí ibi èjó ìkú Olówu. Bí a rí eni tí ó se èyí, a jé pé kì í se dúdú ló bí i.

Bòdé: Báwo ni o se rò pé ejó náà yóò rí?

Kéhìndé: (Ó dédé já lù wón) E má bínú pé mo dédé já lù yìn, òrò yín ló kó wò mí lákínyemí ara. Bí ó tilè se adití ni eni tí ò jókòó sí orí àlééfà ìté ìdájò, yóò dá àwon olópàá lébi.

Láyí: Ní ìlú tí nnkan bá ti dára mà nìyen o, ní ibi tí a kò ti da ojú òfin délè. Ní òdo wa níyìn-ín, èké ni yóò rojó, èké ni yóò dá a. Sùgbón a kò mo nnkan tí adájó èyí lè se sá o.

Bòdé: Bóyá… (Adájó wolé, wón pe “kootu”, gbogbo ènìyàn dáké, wón sì wò sin-in bí obe páànù. Ìdúró ni gbogbo wón wà pèlú, adájó jókòó kí won tó jókòó)

Olá: (Ó dìde láti sòrò) Yorùbá bò wón ní alé emu, òórò isà, kùtùkùtù là á jí ta àgò imò gbígbe. Mo rò pé ejó tí ó ye kí á tètè múra sí kí á parí kíá ni ejó Olówu gégé bí ó se jé. Mo sì rò pé tí nnkan bá ń lo bí a se se ètò rè, yóò férè pari lónìí nítorí náà a ò ní í fi òrò falè. Nígbà tí a ń sún ejó sí iwájú ní ìjelòó, Músá àti Làtí ni wón ń sòrò lówó, òdò won náà la ó sì ti bèrè (Làtí àti Músá dìde).

Músá: Béè ni. E se é, Olúwa mi. (Ó kojú sí Làtí) Nígbà tí o ń bò ní òdò Olówu, ó pe Ògbéni Tìjání dání?

Làtí: Béè ni.

Músá: Ta ló ránsé sí o?

Làtí: Àbú

Músá: Kí ni ìdí tó fi pè ó?

Làtí: Ó so pé Olówu kò tò béè ni kò sì sòrò.

Músá: Ó tán? Nígbà tí ìwo dé ibè, o rí i tí aso Olówu tutù? Làtí: Ó tutù jìn-nì-jin-ni pèlú ìtò

Músá: Ení rè ń kó?

Làtí: Òun náà tutù ó sì ń rùn.

Músá: Won kò sì se nnkan kan nípa rè nígbà tí ìwó wà ní ibè?

Làtí: Wón kò se nnkan kan

Músá: Njé o gbàgbó pé òótó ni pé kò tò?

Làtí: Ó tò kè. Ó tò sí orí eni àti si ara aso rè.

Músá: Njé o tilè mò bóyá wón wè fún un?

Làtí: N kò mò.

Músá: Kò burú. N kò tún ní ìbéèrè kankan báyìí ná. (Àwon méjèèjì lo jókòó, Adé dìde)

Adé: Olúwa mi (Ó kojú sí Olá), Mo fé látí pe onísègùn Hàrámù láti so tirè. Olúwa mi, mo fé kí e ránti pé nígbà tí ilé ejó yòó bèrè ìjókòó ní òórò yìí, òyì orí gbé Hàrámù, tí ó ń pòyì ràndàn, tí ó ń pa ràdà. Mo fé kí ilé ejó bèèrè ní owó rè bóyá ojú rè ti wàlè tàbí ó sì wà ní ara rè (Adé jókòó, Olá dìde, ó kojú sí Hàrámù)

Olá: N gbó, Hàrámù, sé lùkúlùkú tó dà bò ó léèkan ti lo? Sé orí fífó ti fi ó sílè? Sé ojú re sì ti wá da wáí wàyí?

Hàrámù: Gbogbo rè ti lo Olá: Ojú re tí ó ń sú ń kó?

Hàrámù: Ó ti lo. E se é, a dúpé Olá: Aìísìí mò o, ó tun lè dé lójijì o. Sé òjijì là á gbókú adígbónnákú, òjijì sì ni emèrè omo ń bá Olórun lálejò, tí ó bá tún dé, sé o óò tètè so kí á lè mo…

Hàrámù: (Ó dá òrò mó òn lénu) Hówù! Mo se bí òpò onísègùn ló wà níbì àbí kí ni a ti ń se òkú lórun. Tí ó bá tún dé sí mi, won yóò mo ohun tí ó tó tí ó si ye láti se. Olá: Pé won kò ní í jé kódò ó gbárère lo kó? Tó bá jé béè, ká kúkú múse se, àìdúró nijó. (Olá jókòó, Adé dìde)

Adé: Ògùdù níbí ni o ti ń se isé onísègùn

Hàrámù: Béè ni

Adé: Àbú ni ó ránsé pè ó wá sí àgó olópàá? Kí ni ó so fún o?

Hàrámù: Ó so fún mi pé àwon ní eléwòn kan lódò. Ó ní eléwòn pàtàkì ni. Ó ní eléwòn yìí ń pin àwon ìwé kan tí ó lè mú kí a lé oba tí ó wà ní orí oyè wogbó lo pátápátá. Ó ní ó dàbí ìgbà wí pé ara eléwòn yìí kú tùètue sùgbón òun fé kí òun (Hàrámù) se àyèwò sí i bí ó bá se rí. (Ibi yìí ni Músá ti já lù wón tí ó sì gba òrò ní enu Adé, Adé sì lo jókòó)

Músá: Ó tó ìgbàwo kí o tó parí àyèwò re lára aláìsí náà?

Hàrámù: Ó tó wákàtí kan

Músá: O ri i wí pé apá òsì alàìsí náà ti kú?

Hàrámù: Béè ni

Músá: Ó ní ó dàbí ìgbà wí pé esè òsì náà kò sì ní agbára tó bí ó ti ye?

Hàrámù: Mo so béè

Músá: O tún ní bí ènìyàn fi iná jó o pàápàá, bóyá ni ó fi lè fura?

Hàrámù: Mo so béè

Músá: Àpeere burúkú gbáá ni o sì pe eléyìí?

Hàrámù: Nnkan tí ó ń tóka sí ni pé olóògbé náà ti fi opolo sèse.

Músá: Báwo ni a se lè mò pé bí a bá fí iná jó enìyàn lésè kò ní í fura láìfí iná gidi jó o wò? Àbí o fi iná dán olóògbè yìí lára wò ni?

Hàrámù: Rárá o. Òbe kò dára lórùn, iná kò dára lára. N kò fi iná dán olóògbé náà lára wò. Tí a bá so pé kò ní í rí béè tó bá rí béè ń kó? Tí a so pé iná kò ní í jó o kí iná sì wá jo ó. E ò mò pé ìdárànmóràn nù-un, àáyá tó so pé òun yóò tún ojú omo òun se tó ti owó bò ó lójú. A kì í fi iná dán ara ènìyàn wò nítorí kì í se igi.Bí ènìyàn tilè ké igi ní igbó, ó ye kí ó fi òrò ro ara rè wò. Nnkan tí à ń se kó nìyen.

Músá: Kí ni e wa ń se?

Hàrámù: Nnkan tí a máa ń se ni pé a ó rin aláìsàn náà ní àtélesè pèlú ìka, a ó fi rìn ín láti òkè lo sí ìsàlè, tí kò bá fura, a lè mú abéré kí á fi gún un díè wò, tí kò bá tún ti fura, a jé wí pé bí a fi iná ra á lésè pàápàá, kò le fura.

Músá: Kí ni orúko tí a ń pe irú àìsàn yìí?

Hàrámù: Atèmá-fura

Músá: Kí ni ìwúlò rè fún isé yìí?

Hàrámù: Bí atèmá-fura bá ń se ènìyàn, a jé wí pé ó ti fi opolo gbogbé.

Músá: Atèmá-fura ni ó sì ń se é? Làtí náà ní láti se àkíyèsí rè?

Hàrámù: Béè ni. Mo tilè so fún un tó ìgbà méta kí ó jé kí á jo yè é wò. A sì jo yè é wò fín-ní-fín-ní, a yè é wò, a tún un yè wò. Ìgba yen ni mo tó wá té ara mi lórùn pé àrùn ojú ni eléyìí kì í se àrùn inú àbí àrùn tí ó bá ti ń mú ìgbà lo tí ó ń fa òódúnrún dání sáa ti kúrò ní àìperí, mo ní dájú sáká, atèmáfura nì yí.

Músá: Njé ènìyàn lè díbón atèmá-fura

Hàrámù: Ní àádòrùn-ún ìgbà ó lé mésàn-án nínú ogórùn-ún, kò seé se.

Músá: Njé o tún se àkíyèsí nnkan mìíràn?

Hàrámù: Béè ni. A tún se àkíyèsí àìsàn kan tí ó máa ń bá ohùn jà.

Músá: Kí ni orúko rè?

Hàrámù: Àpètúnpè ni à ń pè é

Músá: Kí ni o rò pé ó tún ń fa ìyen?

Hàrámù: Opolo tó fi sèse yìí kan náà ni

Músá: Kí ni ó ń jé àpètúnpè?

Hàrámù: Àpètúnpè ni wí pé kí aláìsàn máa tún òrò tàbí àpólà gbólóhùn tí a bá so sí i pé léralérá. Yóò máa pe òrò inú gbólóhùn yen léraléra

Músá: Fún àpeere, tí a bá so wí pé “Sé o ń gbádùn?” Yóò máa dáhùn wí pé “o ń gbádùn, o ń gbádùn, o ń gbádùn…”

Hàrámù: Rárá o. Yóò so wí pe “ gbá gbá gbá gbádùn …”

Músá: Nítorí nnkan tí o se àkíyèsí yìí, o ní kí won ye ònà tí èjè ń gbà ni inú olóògbé náà wò?

Hàrámù: Béè ni.

Músá: Kí ni ó wá rí?

Hàrámù: Mo rí ìjánjá opolo díèdíè nínú èjè náà

Músá: Báwo ni èyí se se pàtàkì sí nínú àyèwò re?

Hàrámù: Ó ń fi ìdí ohun tí mo ti so télètélé múle ni

Músá: Ní sókí sá, o sá mò wí pé nnkàn ń dààmú Olówu?

Hàrámù: Béè ni

Músá: O sì jé kí Làtí àti Àbú mò wí pé o ti rí àpeere mérin, ó kéré tán, tí ó fi hàn kedere wí pé nnkan ti selè sí opolo Olówu?

Hàrámù: Béè ni

Músá: Àwon àkíyèsí wònyí sì ti selè kí Olówu tó kú?

Hàrámù: Béè ni

Músá: O se é púpò, onísègùn Hàrámù (Àwon méjèèjì lo jókòó) Olá: (Ó dìde) Mo rò wí pé o ti se tán pèlú onísègùn

Hàrámù? Tí ó bá jé béè, n kò ní ìfé láti pe elérìí kankan mó nítorí ejó yìí gbódò dópin lónìí. N ó pe àwon agbejórò wí pé kì won so ti enu won kí ìdájó tó bèrè. Eni tí n ó sì kó pè ni Òjó yèúgè.

Òjó: Nnkan tí a ń se ìwádìí sí ní ilé ejó yìí ni wí pé bóyá àsìse kankan tàbí ìwà ìkà wá láti owó àwon olópàá, àwon onísègùn tàbí àwon tí ó ń tójú eléwòn nípa ikú tí ó pa Olówu. A ti ní èrí pèlú ìdánilójú pé ohun gbogbo ti parí àti wí pé láti nnkan bíi wákàtí méfà sí méjo léyìn ìgbà tí Olówu ti fi ara pa ni eran tí ó bàjé kò ti bèrè sí ní í ní èdò mó tí òró sì ti bèrè sí níí kojá bí a se fi i sí.Ìgbà yìí ni a ti mo wí pé sàn-ngbá ti fó ti pé. Ó sì ti pé tí omóye ti rin ìhòòhò wojà, kò sì sí ohun tí enikéni lè se láti mú aso bá a mó. Nígbà tí yóò fi se díè sí èyí, kò sí nnkan tí àwon olópàá tàbí onísègùn lè se mó láti fi ràn án lówó. Nítorí náà, mo fé kí ilé ejó gbà pèlú mi wí pé ikú tí Olówu kú kì í se láti owó enì kankan, a kò sì lè ka èsè rè si enikéni lórùn.

Olúwa mi, ohun tí ó selè yìí, ohun tí ó seni láàánú púpò ni. Ejó yìí sì jé ejó tí ó kan àwon méjì tí won kò fi agbára féràn ara won, ìyen olópàá ní apá kan, eléwòn ní apá kejì.

Olúwa mi, òrò náà le lóòótó, ó le ó sì gba ogbón, sùgbón àìfi èlè ké ìbòòsí ni ìbòòsí kò seé jó, bí ojú bá fi ara balè, yóò rímú. Bí yànmùyánmú bá bà lé ni ní ibi tí kò dára, sùúrù ni a fí ń yanjú rè. Kiní òhún só sí ni lénu tán ó tún buyò sí i, isó ò séé pónlá, iyò ò seé tu dànù. Omi ló bù sí ni lénu tó ní kí á máa féná, iná ò gbodò kú omi ò sì gbodò jò dànù. Eni tí ó ki towótesè bo ègún kò gbodò kánjú, sùúrù ni a ó nà sí i, olúwa mi, tí a ó fi yanjú gbogbo rè pátápátá.

A kò gbodò fi bó se rí sílè kí á máa tanná wá báyìí ló se ye ó rí kiri. Nítorí ìdí èyí, olúwa mi, nnkan tí àwa yóò so fún ilé ejó yìí ni wí pé a kò rí àsìse kankan láti owó enikéni tí a lè so wí pé òun ni ó fa ikú Olówu, tó fi bèrè láti orí àwon olópàá, awon onísègùn àti àwon tí ó ń se ìtójú eléwòn. Irú ojú yìí ni a ó fé kí adájó bá wa fi wo ejó yìí.

Olá: O se é púpò Òjó, òrò kàn ó, Adé.

Adé: Olúwa mi, láti ìgbà díè séyìn, a ti gbó a sì ti rí òpòlopò nnkan èrí ní ilé ejó yìí.

Olúwa mi, òpò ìgbà ni àánú àwon olópàá máa ń se mí. Òro won dà bí òbúko. Òbúko ní àìsàn olówó òun yìí ń ko òun ní ominú, ó ń ba òun lérù pèlú. O ní bí ó sàn fún un, won yóò fi òun wú ewu àmódi, bó sì kú èwè, won yóò fi òun se àríyá òkú. Báyìí gélé ni òrò àwon olópàá se rí tí àánú won fi máa ń se mí Sùgbón a dúpé, a ní irú ilé ejó yìí. Wón ní aríléróde kì í jeun àwùjo tì, àse lásán loba ń pa, gbajúmò gidi ló nìlú, a ó máa rí yín bá.

Gégé bí mo ti so, láti ìgbà tí ejó yìí ti bèrè bí ijó méta séyìn ni a ti ń gbó orísírísi èrí ní ilé ejó yìí ní òkankòjòkan. Oníwá ti wí, tèmèdò ti fò, èyí tí ó jé kókó tí a sì rí dìmú jù lo gégé bí òótó ni wí pé, ní àgó àwon olópàá, nnkan fé sí Olówu lára. Nnkan tí ó sì seé se, nnkan tí ó lè selè, nnkan tí a sì lè fi ojú dá ni wí pé nínú gbàwòsí-n-ò-gbàwòsí, gbónmi-si-i-omi-ò-tó-o tó tèlé e ni Olówu ti fi orí pa. Eni tí ó bá sì so wí pé se ni àwon olópàá tó ń tójú Olówu fi nnkan gbá a lórí kò fi ara balè fi etí sí gbogbo èrí tí ó ti ń wá sí ilé ejó yìí, ìyá oba ni ó sì fi ń pe ìyá ebo, ó sì ti gbàgbé pé kò sí ojú ogbé yànmòkàn yanmokan kankan lára Olówu láti fi hàn pé se ni àwon olópàá fi ìyá je é. Hábà! mo se bí bá a tilè gbáni létí lásán, ó ye kówó ó lé pòndànràn pondanran létí eni ábòntórí kóńdó baba egba!

Èsùn tí òré mi fi kan àwon olópàá wí pé wón fi ìyá je Olówu kò mú iná dé oko rárá. Ń se ni ó gbé èro rè lórí àwáwí àti àsodùn tàbí pé o fé kí owó àwon mòlébí Olówu te àwon olópàá tó ń mú ojú tó ìdáàbòbò ìlú. Ó ti gbàgbé pé rírò ni ti ènìyàn, síse ń be lówó Olórun Oba. Bí òré mi se ń ro ejó, ó dàbí ìgba pé o wù ú láti yí òfin tí ó de àwon olópàá padà, ó fé mo ìdí abájò, ó fe mo àtisùn Olórun oba, ó fé mo ìséjú akàn, ó fé ri fìn-ín-ìn ìdi kókó, iró sì ni, kò ní í lè se é. Òré mi kò fi èlè wádìí òrò lówó àwon ènìyàn mi. Lóòótó, tómo ení bá dára ká wí, Ògbéni Músá se isé rè bí isé. Ó se é gidi ni. Ó se wàhálà púpò. Gbogbo nnkan tí ó ye kí ó mò nípa ikú Olówu ni ó se ìwádìí fín-nífínní. Fún èyí, ó ye kí á kí i, kí á yìn ín.

Sùgbón lékèe gbogbo èyí, kí ni àbáyorí? Ojó ojà? òfo ni, ojó kejì ojà sì tún ń kó èwè, òfo náà ní. A ti gbó èrí. Ti wí pé a kò rí èrí kankan dìmú tí ó so wí pé àwon olópàá fi ìyà je Olówu nìkan kó, a tún rí i wí pé opolo tí Olówu fi pa ni ó se ikú pa á àti wí pé kò sí èdá alààyè kankan tí ó ní owó nínú ikú Olówu.

Gbómo sílè kó o gbe ohun mìíràn, àfi eni tí yóò gbé gbèsè. N kò rò wí pé oré mi tún lè rí nnkan kan so lórí òrò yìí mó ju èyí tí wón ti so yen lo. Nítorí ìdí èyí, olúwa mí, inú mi yóò dùn tí e bá lè gba èyí tí mo so yìí yèwó kí e fa ìwé ejó ya. Olá: O se é Adé, Ògbéni Músá, ó kàn ó.

Músá: Olúwa mi, lóri ejó yìí, ilé ejó ti gba èrí. Gégé bí òfin sì se so, alé níí kéyìn òsán, léyìn ìgbà tí ilé ejó ti gbó láti enu iwá àti èyìn tán, tí lágbájá ti wí, ti dóòlà fò, tí lámorín so, tí tèmèdò fò, tí a ti gbó ti enu àlérépèté gégé bí Ògbéni Adé se so, nnkan tí ó kàn ni wí pé kí ilé ejó so nnkan tí ó rí.

Wón ní Olórun nìkan ni ó lè se èrí afeyínpínran àti wí pé èèyàn méjì ni òrò máa ń dùn lénu won, arúgbó àti àlejò nítorí wí pé a kò lè já won. Arúgbó yóò so pé kí won tó bí ènìyàn ni ó ti selè, àlejò yóò so pé ní ìlú àwon lóhùn-ún ni ó ti selè. Won a tún máa so pé ohun tí ojú ènìyàn kò tó, ojú Olórun nìkan ló tó o. Sùgbón kì í se gbogbo ìgbà ni eléyìí máa ń rí béè. Ohun tójú èèyàn ò tó, a lè fogbón orí gbé e.Won ní bí a kò se ode rí, a ó mo esè nnkan tí kò tí ì lo. Enìyàn ò sá ní í dijú ká tó fòru hàn. Okùn iró báyìí, péré ní í já àbí omodé tó dé ilé ayé tó ní odoó ni wón ń ra aso ní òrun, ó rí béè lòun rin ìhòòhò wá sí ilé ayé? Eni tí ó bá ti rí ejò tí ó ń fi àìlówó, àìlésé gun igi ti ye kí ó mò pé ejò lówó nínú. Ijó àwé náà ni yóò bó àwé láso, inú òró tí àwon olópàá so sìlé náà nì a ti rí òkodoro òrò.

Eni tí ó kú tí à ń so òro rè yìí ni à n pè ní Olówu. Nípa ti nnkan tí ó pa á, kò sí tàbí sùgbón nítorí tàbí, sùgbón, àmó, iró ní ń jé béè. Àwon onísègùn tí ó ń ye opolo wò ti so wí pe opolo tí ó fi pa ni ó se ikú pa á àti wí pé ń se ni wón na nnkan mó on lórí kì í se wí pé ó déédéé fi pa.

Mo lè se àláyé ráńpé lórí nnkan tí a rí kà nínú àkosílè àwon olópàá wí pé ń se ni Olówu kò tí kò jeun tàbí wí pé ń se ni kíndìnrín ń dùn ún. Àwáwí ni eléyìí, iró pátápátá sì ni pèlú, a kò sì lè gbà á wolé rárá. Hówù! ta ní kò mo ibi tóbìnrin fi ń fún fúsáárí té e wá ń so pé kó kèyìn sígbó. Nnkan tí emi yóò so yóò yàtò pátápátá sí nnkan tí àwon kan ń so pé omi kò lè sàn kàn ara kó má sàn wonú ara, wí pé gbónmi-sí-i-omi-ò-tó-o tí ó selè láàrin àwon olópàá àti Olówu ni ó fa orí tó fi pa. Hábá! mo se bí mápá eran wá, a máa jé mápá eran wá, mútan eran wá, a máa jé mútan eran wá, mú gèngè àyà wá sì ń kó èwè, a máa jé mú gèngè àyà wá, sùgbón mú eran wá nínú ajere, eran àrííriì lèmí kà á sí, òjóóró sì ló wà ní ìdí rè. Èmi ò gbà wí pé èdè àìyedè ti ó selè láàrin Olówu àti olópàá ni ó fa orí tí ó fi sèse. Nnkan tí èmi yóò so ni wí pé òkan tàbí púpó nínú àwon olópàá yìí ni ó fa orí tí Olówu fi pa tí ó sì fa ikú rè. Pòn-ún òhún se ògangan ìdí púpò jù. Yàtò sí èyí, ó tún ní láti jé wí pé olópàá òhún mò-ón-mò se é ni, ìfé inú rè ni ó fi se é pèlú, láìnídìí, láìtèlé òfin kankan ní ilè wa, won kò ní ètó rárá àti rárá láti se béè. Òrò ti wí pé ó sèèsì kò sì sí ní ibè pèlú. Bí ó tilè sèesì, nnkan tí ó bá wá ní inú eni ni otí máa ń pani bá àti pàápàá kò tilè sèèsì.

Olówu kú ikú tí kò dáà. Ń se ni ó kú ikú omo tí kò ní ìyá, ní orí ení, ní inú ègbin àti ìyá, nínú ogbà èwòn láti owó àwon asekúpani. Bí ènìyàn yóò tilè pa eran iléya yóò se àdúrà. Ikú adìye ìrànà sàn jù ti Olówu. Àwon tí ó sì se béè sí i jèbi láyé, won yóò sì tún jèbi lórun.

Ohun tí a rí dájú ni pé won mú Olówu lo sí àgó olópàá pèlú ara líle àti eegun tó pé. Nígbà tí ó dé ibé, léyekòsokà, àwon eni ibi ti ba ayé rè jé, àti opolo àti ara rè, kò sí èyí tí ó pé mó. Èyí fi hàn wí pé nígbà tí Olówu wà ní òdò àwon olópàá ni nnkan tí ó selè sí i selè sí i. Àbí, àjé ti se wá ké lánàá tí omo sì kú lónìí, e tún ń wádìí ohun tó pomo, ohun tó pomo ti fira rè han. Nnkan tí kò jé kí àwon ènìyàn fé so òtító ni èrù àwon olópàá tí ó ń bà wón, ta ni omo aperin níwájú omo apààyàn? Ó se, iró bèrè sí gorí ara won, dúdú ń gun funfun, pupa ń gun dúdú. Lámorín so wí pé òun kò rí i kí nnkankan se Olówu, Tèmèdò ní ń se ni ara Olówu le bíi kongí. E ò rí ayé lóde, kàyééfì gbáà!

Wón ní òrò àsotì ní ń jé omo mi gbénà. Àti Àbú àti àwon onísègùn rè, ń se ni wón jo di ìmò òtè pò. Won kò ro ti aláìsàn tí ó wà ní abé ìtójú won. Tí ó bá jé pé àwon onísègùn ro èyí ni, ko ye kí won máa fi ìgbà gbogbo jé hòo hòo fún Àbú. Kò ye kí won gbà kí Àbú máa hu ìwà tí kò bá òfin mu kí ó sì máa darí wón bí èfúùfùlèlè se ń darí ìgbé. Inú àwon olópàá ti dùn, okàn won sì ti bale wí pé ibi tí ó bá wú olówo eni níí ránní lo, èyí tí àwon bá ti so pé kí àwon onísègùn se ni won yóò se, àjé òrun kì í sáà rójú bá táyé wíjó. Lóòótó, nnkan tí won rò se, èyí sì mú kí okàn won balè. Ìbàlè okàn tí awon onísègùn fún won yìí ni ó jé kí won wá sí ilé ejó wá máa to ìtòkutò nípa ikú Olówu. Wón wá ń so pé ìgbà tí àwon àti Olówu ń já ìjàkadì ni nnkan se é, àwon kó ló fi nnkan se é fúnra àwon. Wón ní aféfé kò fé, ń se ni a dédé rí ìdí adìye. Wón ni ń se ni ó díbón nígbà tí ó jé wí pé kò sí eni tí yóò rí i tí kò níí mò pé ó ti di òkú tan. Hè è è, kò kúkú sí ní owó ajá tó já, àwon tó so ó ni kò só o re. Eni tí ó bá sì kò tí kò bá kó ogbón nílé, a jé wí pé òde ni yóò ti kó ogbón wálé. Bí ògá àwon olópàá yìí bá kò tí won kò so ajá won dáadáa, tí won kò tí won kò kó omo won lógbón láti ilé, ilé ejó yìí náà ni yóò bá wa so fún won wí pé kí won ki owó omo won boso, a kì í lo agbára ní ìlòkulò. Kí won bá wa fi ìyà je onírìkísí, ajunilo kò sá ní í ju Olórun lo. Nnkan tí mo ń fi sí iwájú ilé ejó yìí ni ó jé òtító àti òdodo. Àwa kò níí yé so òtító títí tí bèlá yóò fi fun fèrè. A kò ní í bèrù ènìyàn kí á se Olórun. Bí òtító se korò tó, àwa yóò so ó fun aráyé bí ó ti wù kí ó rí. Ó ye kí á fi yé aráyé wí pé ń se ni òkan tàbí púpò nínú àwon olópàá yìí fi ìyà je Olówu títí tí wón fi pa á. A fún won só, wón sì lù ú pa. A ní kí won dín in gbe, wón dín in jóná. A ní ki wón gbé e rébété, wón kán an pón-ún. Ó ye kí á fi ti won jé ofin wí pé enìkan kì í jé àwádé, òpò ènìyàn ní í jé jànmó-òn, wí pé àwa la wà ńbè ní í bàlúú jé, wí pé èmí omo ènìyàn kúrò ní ohun tí à ń se sìbásìbo. Ìdí odán ni wón pè ní yàrá òbo, ilé ìdájó yìí náà ni ibi ìgbàlà ìkeyìn, ní ibi tí a ó ti rí ìdí òkodoro tí gba-n-gba yóò dekùn, tí kedere yóò bè é wò. Ìdájó tí ó ye kí ilé ejó dá ni èyí ti kò ní í fi àyè gba àwon tí agbára wà ní owó won láti lò ó ní ìlòkulò. Ìdájó tí yóò mú àyà onítèmbèlèkun èdá já gbàmù. A ń reti ìdájó báyìí láti enu adájó. Àbò mi rè é o, Olúwa mi.

[Àwon adájó dìde wo inú yàrá kékeré kan lo láti lo foríkorí. Ìgbà tí wón jáde tán ni èyí àgbà nínú won wá ka ìdájó jáde.]


Adájó: Nnkan tí a rí nì yí, n ó sì da ejó náà báyìí, mo sì fi òfin ti òró mi léyìn, àse ń be lórí rè pèlú. A mo òkú olóògbé yìí sí ti Olówu. Orí fífipa pèlú opolo fífi sèse ni ó fa ikú rè nítorí ó da èjè rè láàmú púpò. Ó ní láti jé wí pé olóògbé yìí fi orí yìí pa ní ibi tí hówùhówù ti bé sílè láàrin òun àti àwon olópàá ni. Pèlú àyèwò tí a se, a rí í wí pé enì kankan kò jèbi fún ìfarapa yìí kò sì si eni tí ó se àsìse kankan nípa ohun tí ó se ikú pa Olówu.

Èyí ni ìdájó mi.

[Wón pariwo, adájó jáde, àwon ènìyàn náà sì ń jáde pèlú ìrònú, Músá sì bó sí ojú agbo.]

Músá: Òrò ni e ri yen o, èyin ènìyàn wa. Wón ní ikú tí ó ń pa ojúgbà eni, òwe ni ó ń pa sí ni. Bó bá dára béè... [Ó fi orí ìtàgé sílè, iná kú]

ÒPIN ERÉ.

[edit] ÀWON ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ

(ÒRÒ ÀKÓSO)

Eégúnlégi - Ènìyàn pàtàkì Orò, oko fúnfun - Eni tí kò bèrù àwon Òyìnbó. Ó tilè ń dà wón láàmú. Jàjàgbara - Jà láti gba ara eni sílè nínú ìdè, jà fún òmìnira Nípa adìye ìrànà - Ní ìpa adìye ìrànà. Adìye ìrànà - Adìye tí a máa ń tu ní ààyè nígbà tí òkú bá kú láti fi ra òná fún òkú. Gúsù Aáfíríkà - Ní ibi tí àwon ènìyàn funfun ti ń fi ìyà je ènìyàn dúdú tí ó jé onílè nígbà kan rí. Déènà penu - Gbara ní àsìkò. Gba àsìkò púpò.


[edit] ÌRAN KÌÍNÍ

(ÌDI MÒGÚN NÍ ÌLÚ ÒGÙDÙ)

Olùsìn - Àwon tí ó jé wí pé Mògún ni wón ń sìn.

Òlùbo - Olórí àwon tí ó ń sin Mògún.

Fògèdè móyán - Yorùbá gbàgbó pé tálákà ni ó máa ń fi ògèdè àgbagbà mó iyán kí ó lè tóó je, olówó kìí sè é.

Gbékù lo … gbárùn lo - Ti ibi gbogbo jìnà si ni.

Yèé a wí, Mògún gbó - Eleyìí tí a so, Mògùn gbó.

Dàńsáákì - Kí á kan sáárá sí nnkan. Kí á yin nnkan

Mú ònà òdò rè pòn - Bèré sí lo sí òdò rè.

[edit] ÌRAN KEJÌ

(ÌSÒ ONÍGBÀJÁMÒ)

Póun                               -       Pé òun 

Kíná má kó wo eni náà nírun - Kí kòkòro tí ó ń wo irun eni tí irun rè bá kún má se wo irun òun.

Eja òfóòrò - Eja tí a pa lóòjó

Omíyale - Kí òjò rò púpò débi pé ó ń ya wonú ilé ó ń kó erù lo.

Mèháyà - Eni tí ó ń yá ilé gbé

Aso ara awo, aso bánbákú - Aso náà ni awo yóò wò títí tí yóò fi kú.

Kàn mí dà nínú òkú ìyá Àdèlé - Kò sí nnkan tí ó kàn mí ni ibè. Sé a mò pé oba Èkó nígbà kan rí ni Àdèlé, n kò sì rò pe ikú ìyá rè le kan gbogbo ará aye ní pàtàkì eni tí kì í bá se Èkó ni ìlú rè. Kí á tilè so pé Ekó ni a ti bí ènìyàn pàápàá, àwon ará Èkó kì í ka nnkan sí tó béè jù béè lo. Irú wá ògìrì wá ni àwon ènìyàn tó wà ní Èkó.

Ràkúnmí- Eranko tí ó ní òkìkí fún fífi ara da òngbe. Ìgbà tí ó sì ti jé pe ilè tí omi kò wópò sí ni ilè àwon Gàmbàrí, wón kúndùn láti máa ní irú eranko yìí.

Ìrábàbà - Ìdà láàmú

Ìpayínkeke - Wíwa eyín pò léyìn ekún ìgbá pípé.

Pààrò - Ká gba nnkan ní owó ènìyàn kí á fún un ní nnkan mìíràn tí kì í se owó.

Àróbò - Adìye ni ó dúró fún níbí.

Òrí - Òróró láti inú èso igi kan. ó lè dì, sùgbón tí òòrun bá pa á, yóò yó.

Lèmómù - Òkan nínú olórí àwon Mùsùlùmí

Sàwátì - Se awátì

Obìin - Obìnrin

Bèéní - Béńjáméènì

[edit] ÌRAN KÉÈTA

(ILÉ OLÓWU)

Ara mi ni isó ti ń rùn - Èmi ni òrò selè sí.

Ìjoba amèyà - Ìjoba tí ó ń se ènìyàn funfun dáradára tí ó ń lo ènìyàn dúdú ní ìlòkulò.

Abó olómi góòlù - Abó tí a fi àwò góòlù se òsó sí ni ara.

Fi owó bà á - Gbà á béè.

Obì níí bàrùn - Obì níí bi àrùn

Òrò Sùnnùkùn - Òrò búrúkú.

Òrànfè - Òrìsa kan ní Ilé-Ifè.

Olúgàn-nbe - Òbe tí ó se enu sómúsómú

[edit] ÌRAN KÉÈRIN

(ILÉ LÓÓYÀ)

Séńbà - Yàrá kékeré tí a máa ń kó mó ilé isé tí àwon ògá isé, ní pàtákì, àwon agbejórò, máa ń jókòó sí.

Ìgèrè - Pàkúté tí a fi ń mú eja nínú odò.

Òdú - Orísìí èfó kan

Béèlì - Gbígba ìdúró fún òdaràn kí á lè tú u sílè títí tí ojó ejó yóò fi pé.

Àkò - Ilé òbe tí a fi awo se.

Asín - Ekú kan tí enu rè gùn gbooro. Ó ń rùn púpò.

Kàfó - Oparun tí a gbé rebete tí a ń ki sìgá sí nínú láti mu. Ó lè jé igi náà ni a se béè gbé.

Apokoje - Eni tí ó ń pa oko je. Obìnrin tí ikú oko ń wá láti owó rè.

Kèrè - Agolo kékéré tí a fi ń bu omi nínú àmù.

Tòyá è - To ìyá rè.

Èlà ìwòrì Atáyéro - Eni tí ó dà bíi Jéésù fún àwonYorùbá. Omo Olúorogbo ni.

Ko lóminú - Bà lérù

Wáwá - Òun ni wón mò sí eni tí ó dá ode sílè nílé ayé.

Gbúèdè - Olùgbúèdè. Òun ni a mò sí eni tí ó dá ode síse sílè lórun.


Èsówéré elémèso - Àwon ìgìrìpá ni ó dúró fún níyìn-ín.

Ìjòwòjówó - Èyí tí kò dára lára eran. Àwon ìjànjá.

Kùsà - Ihò tí a ti ń rí àwon ohun àlùmó-ón-nì nínú ilè.

Rárá díè - Nnkan díè

Rárá fé - Àìtìlè níí rí rárá. Kí ènìyàn máà rí nnkan kan rárá.

Ilé kóróbójó - Ilé kékeré.

Sáké - Wá okùn tí a fi ń di òrùlé.

Wókùn - Wá okùn

Bágara - Bí agara. Ìnira. Bí ará se ń nini.

Dánrùn wò - Dán orùn wò.

[edit] ÌRAN KARÙN-ÚN

(ILÉ BABALÁWO)

Méèjì àdìbò - Mú eéjì àdìbò – owó tí a ó fi bèèrè òrò lówó ifá Mééta ìténí - Mú eéta ìténí. Ara owó tí a ó fi bèèrè òrò lówó ifá náà ni eléyìí. Kàrì - Odù tí ó ti fò nínú ayò olópón. Gùru - Odù eléyìí tún ju kàrì lo. A díá fún - A dá ifá fún Ota arò ògún - Àdó tí a ń ro ètù sí Tòròfíní - Orísìí èkúté kan. Alùkòrè ayé - Eni tí gbogbo ayé ń lo sí òdò rè láti mo bí nnkan yóò se rí. Alùyàn-ndà Olódùmarè- Eni tí ó ń se ojú fún Olódùmarè. Kiriyó - Onígbàgbó Wútùwútù yakí - Ède lárúbáwá kan ni eléyìí. Wútùwútù yán-nbele - Ède lárúbáwá náà ni èyí láti fi hàn pé ifá sòrò nípa èsìn Mùsùlùmí. Páríkòkò - Ohùn enu dùndún Párigidi - Ohùn enu bàtá Òyà - Owó isé.

[edit] ÌRAN KEFÀ

(ÀGÓ OLÓPÀÁ)

Àgó Olópàá - Ilé isé àwon olópàá

Òkè-ilè - Àìsàn burúkú. Sànpònná

Ìsín - Eja kékeré

Kóro - Ape tí a fi ń yo irin

Lùkúlùkú - Àìsàn burúkú kan

Gòbì - Iwájú ilé ní ibi tí ìjòyè gbé ń gba àlejò.

Folo fóló, Sonbí - Eni tí ó ń se nnkan láìronú tí ó jé wí pé èyí tí a bá ti so fún un náà ni yóò se.

Móríyìíná - Eni tí ó máa ń so ohun tí ojú rè tó àti èyí tí kò tó.

Eja-n-bakàn - Eja tàbi akàn. Eja kò dára. Akàn ni ó dúrò fún nnkan tó dára.

Gúdúgúdú - Ìlù kékeré ti a máa ń fi awo kéékèèkéé pelebe méjì lù.

Òpìpì - Adìye tí kò ní ìyé púpò lára

Kánrinkánse - Láéláé. Títí ayé.

Wóńwé - Tí kò pò

Wàrànsesà - Kíákíá. Wéréwéré

Gíífà - Kí nnkan kú láìjé pé a fi òbe dú u lórùn. Sùgbón ní ibí yìí, ó dúró fún òkú tí a kò tójú.

[edit] ÌRAN KÉÈJE

(INÚ ILÉ KAN NÍ ÒGÙDÚ)

Túú ló ń rú - Kò jóná. Ń se ló ń rú túú. Ó ń se èéfí. Tara pàpà lo Àpápá - Sáré lo sí Àpápá. Ìfòròseré ni eléyìí. Igi mímí - Igi tí kò gbe. Gòlúgò - Eranko kékeré kan tí ó féràn àbàtà púpò. Sé Múrí - Sé Ogún Náírà. Agbè - Akèrègbè Légédé - Orísìí èfó kan Kélésè mésè le - Kí á múra sí esè fífi rìn. Bèlá yóò fun fèrè - Òpin ayé. Kurumó - Àwon ará ìlu Làìbéríà, Ilé ènìyàn dúdú kan. Gbòndí gbúù - Fi owó gbón ìdí nù. Sàn-ngbà fó - Nnkan bàjé.

[edit] ÌRAN KÉÈJO

(NÍ KÓÒTÙ)

Òrò kòbákùngbé - Òrò tí kò dára .

Wíjó lo kánrin - Wón so òrò lo bí ilè bí ení.

Láìfòtá pè - Láìwo ti òtá.

Òkolonbo - ìhòòhò.

Túbú - Ogbà èwòn

Tànmó-òn sí mi - Yé mi sí i. So sí mi lókàn.

Lanúlanú - La inú la inú. Eni tí ó ń la inú.

Pófunpófun - Pó ìfun pó ìfun. Eni tí ó ń pó ìfun.

Àpólúkú - Àpò tí oúnje ń lo sí inú rè nínú ikùn.

Keríkerì - Orísìí ìlù kan.

Dá a ní ménu - So pé kó dáké.

[edit] ÌRAN KÉSÀN-ÁN

Ònwòran - Àwon tí ó ń wòran.

Àtàláátà - Ojó keta òsè Onígbàgbó. Atàláátà ni àwon Mùsùlùmí ń pè

                                                   Túsìdeè 

Àlààrùba - Ojó kejì Àtàláátà tí ó jé Ojórú ní Yorùbá, Wésìdeè.

Jémi lóni - Jé kí n ní ènìyàn.

Kólédafé - Kó ilé de afé síse

Akékarakara - Eni tí ó ń pariwo sókè.

Aréweyò - Eni tí ó ń yò mó èwe; eni tí ó ń yò mó àwon omodé

Dáradóhùn - Eni tí ó dára títí dé ohùn.

Òbòró ojú - Ojú tí a kò ko ilà sí.

Apó - Ilé tí a ń fi ofà sí.Ohun tí a ń fi oògùn búburú sí inú rè

Ìpà ode - Orò tí á ń se léyìn ikú ode.

Láìsosè - Láìso esè. Láìdúró.

Pínnísín - Omo owó.

Sèkèté - Otí tí a fi àgbàdo se.

Agadagídì - Otí tí a fi ògède tí ó pón tí ó férè rà se.

Gbégbó - Gbé igbó.

Gbégbèé - Gbé ìgbé.

Mò-ón-mò - Mòhámádù.

[edit] ÌRAN KÉWÀÁ

(NÍ KÓÒTÙ)

Tàkùròso - Wón ń bá ara sòro pàápàá òrò èfè.

Gùùkàn èyìn - Bí iké se máa ń yo sí ìta.

Akínyemí ara - Ibi tí ó káni lára jù ní ara

Àlééfà - Ìjókòó ìdájó tàbí ìjòkòó olóyè kan.

Àwon Mùsùlùmí ni ó sábà máa ń so èyí.

Isà - Emu tí ó ti gbé odidi ojó kan. Ó ti di emu ojó kejì.

Àgò - Ilé tí a fi imò hun tí a fi ń kó adìye .

Adígbónnákú - Irú kòkòro kan. Bí a bá tó o, yóò se bí eni pé ó ti kú. Òrá kò sí ní ara rè púpò

Emèrè - Àbíkú omo. Omo tí ó ní egbé

Arère - Orísìí igi ńlá kan.

Aláìsí - Eni tí kò sí mó. Eni tí ó ti kú. Eni tí ó ti dolóògbé.

Àáyá - Orúko irúfé òbo kan, ìjímèrè

Ìjànjá - Pinpin sí ònà kéékèèke. Eran kékeré.

Ìbòòsí - Lílogun. Kíkégbe.

Fún sáárí - Lo tò.

Àrííriì - Iró.

Òjóóró - Àìsòdodo, ìréje.

[edit] ÌBÉÈRÈ

[edit] ÌRAN KÌN-ÍN-NÍ

1. Ta ni onílé orókè?

2. Kí ni won kò níí fún un je mó?

3. Kí ni wón ní kí Mògún gbé lo?

4. Kí ni won yóò fi se ètùtù fóun Mògún

5. Ètùtù kí ni won yóò se?

6. Tí won bá ko ebè, ta nu ó ń so eni tí yóò? je é?

7. Nítorí kí ni wón se fé se ètùtù?

8. Ta ni ó dá àwon ènìyàn tí ó ń korin ní ménu?

9. Ta ni idà, ta sì ni jagunjagun tí ó mú un dání?

10. Irú obì wo mi wón dà ní ìdí Mògún?

11. “Eni tí à ń wí, ó dé” Ta ni eni tí a ń wí

12. Báwo ni Olùbo àti Olówu se kí ara won?

13. Òsán ni won ń bo Mògún. Kin i ohun ti wón se tí ó yani lénu?

14. Kí ni ‘eye’ tóka sí nínú “eye tó su wá?

15. “Ayò abara tín-ń-tín” Kí ni ìtumò àyolò yìí ní orí kìn-ín-ní yìí?

[edit] ÌRAN KEJÌ

1. Àwon won i onígbàjámò?

2. Kí ni ó lè lékè ayé?

3. Kí ni kò ti sé kí Jímóòn wá fá irun rè

4. Àwon won i irun won lè kún yàwìrì?

[edit] ÌDÁHÙN

ÌRAN KÌN-ÍN-NÍ

1. Mògún ni onílé orókè

2. Ògèdè àti isu lásán

3. Ìkú àti àrùn ni wón ní kí Mògún gbé lo

4. Ajá ńlá ni won yóò fi se ètùtù fún Mògún

5. Won yóò se ètùtù owó àti ètùtù omo àti pé kí àwon má se kábàámò

6. Mògún ni ó ń mú isu won hù

7. Wón fé se ètùtù nítorí owó àti omo

8. Olùbo ni ó dá won ní ménu

9. Àwon olùsìn ni idà, Mògún ni jagunjagun tí ó mú un dání

10. Wón da obì ajóòópá

11. Olówu ni wón ń bá wí

12. Wón gba owó ológun

13. Wón tan ína òsán

14. Àwon òbí wa ni ó tóka sí

15. Ayò tí wón ń yò ní ojú ìbo ni wón fi tako olópàá tí ó wá mú Olówu.